Testimony Jaga: Ṣé èmi ọmọ alágbàdo, ọmọ orí títì ni ẹ̀mí ń lò báyìí?

Testimony Jaga: Ṣé èmi ọmọ alágbàdo, ọmọ orí títì ni ẹ̀mí ń lò báyìí?

A fẹrẹẹ ma le pe e ni olorin to ṣẹṣẹ n yọri soke mọ tori ọna ti orin rẹ gba jale jako ko ye ni mọ.

A fi bii ina to n ran to si ti n sare burẹkẹ.

Eyi ṣeese ko jẹ pe iru ohun ti awọn eeyan n fẹ ni awọn orin to n gbe jade.

Olorin ẹmi ni awọn kan n pe e ti awọn mii si pin in si isọri olorin Fuji tabi takasufe.

Jaga jẹ ọkan lara awọn to ti tan ina sinu agbo orin Kristẹni lọdun 2019 yii.

Ara ọtọ ni orin rẹ to si ni imisi ninu pẹlu ọna ti o maa n gba gbe e jade.

Oríṣun àwòrán, Testimony Jaga

Bi ifede ti ẹmi fọ eyi to maa n waye laarin awọn Kristẹni ni orin rẹ ṣe maa n ri tabi ka tun juwe rẹ bi ẹni to n fa aaya eleyi ti awọn ijọ alaṣọ funfun maa n saba ṣe.

Nigba kuugba ti Mr Jaga ba ti n ṣe eyi, o sọ fun BBC yoruba wi pe ẹmi Ọlọrun maa n sọkalẹ sara oun ti yoo si tun ba le awọn to ba wa ni ipejọpọ naa.

"Mo ṣì ń gba ìpé lórí ìjẹ́rìí àwọn èèyàn tó ń gbọ́ orin mi. Ko ye emi naa bo ṣe n ṣẹlẹ, mi ò mọ bó ṣe ń ṣe mí mọ́, agbára Ọlọ̀run yẹn pọ̀ gan lára mi".

Oríṣun àwòrán, Testimony Jaga

Ọmọ ijọ nla nni, Christ Embassy nii ṣe eyi ti Pasitọ Chris Oyakhilome jẹ oludasilẹ rẹ.

Ogbeni Jaga sọ pe nigbakuugba ti oun ba n kọ orin, Pasitọ Oyakhilome gan an kii le jokoo tori agbara ẹmi mimọ to n ri.