Immigration: Gbogbo òṣìṣẹ́wa pátá ni yóò ṣe àyẹ̀wò òògùn olóró

Ileeṣẹ to n ri si iwọlewọde ajoji Image copyright @nigimmigration

Ati ọga patapata ati ọmọ iṣẹ tabi oṣiṣẹ to kere ju ni ileeṣẹ to n ri si iwọlewọde ajoji ni Naijiria ni yoo ṣe ayẹwo oogun oloro.

Oludari agba ileeṣẹ naa, Mohammad Babandede ati gbogbo oṣiṣẹ ileeṣẹ naa ni yoo ṣe ayẹwo naa.

Gẹgẹ bi alukoro ileeṣẹ naa ṣe sọ ọ, Ọgagun Babandede fi ọrọ yii lede nibi akanṣe eto ayipada ilana ẹkọ ni ile ẹkọ akọkọ ti ileeṣẹ to n ri si iwọle wọde ajoji ni ipinlẹ Kano.

Babandede ṣalaye pe eredi fun ayẹwo yii ni lati jẹ ki awọn oṣiṣẹ ṣ iṣẹ wọn daadaa gẹgẹ bi akọṣẹmọṣẹ.

O tẹnu mọ ọ pe ki wọn ṣọra nipa bi wọn ṣe n gbé ohun ija lẹnu iṣẹ wọn o si fi aridaju han pe ẹni ti ayẹwo naa ba mu, wn o ni kọkọ yọ ọ niṣẹ.

O ni "a o ni kọkọ le ẹni ti ayẹwo ba mu, dipo bẹẹ, a o ko wọn jọ fun ikọni. Bi ẹnikẹni ko ba wa yiwa pada, awọn alaṣẹ yoo gbe igbesẹ lati ṣe ijiya to ba tọ.

Gbogbo ojú la fi ń ṣọ́ Nàìjíríà báyìí lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn - ilẹ̀ Amẹ́ríkà

Ọlọ̀pàá yìnbọn pa akẹgbẹ́ rẹ̀ tán, lo bá pa ara rẹ̀ náà l'Abuja

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionǸkan tí ẹ̀mí mímọ́ fi hàn mí kí n tó bẹ̀rẹ̀ orin ìfèdèfọ̀ rèé- Testimony Jaga

"Gbogbo oṣiṣẹ pata ni yoo ṣe ayẹwo naa bẹrẹ latori emi", lohun ti Babandede sọ.

Bakan naa lori ọrọ yiyẹ aṣẹ irina wo kete ti eeyan ba ti de orilẹede Naijiria eyi ti wọn pe ni "Visa on Arrival", o ni yoo jẹ anfani nla fun awọn oniṣowo ọmọ Afirika to ba n bọ lati wa ṣe owo lọna to tọ ki wn le gberu sii. Bakan naa fun ibaṣepọ to danmọran ti yoo fọ gbogbo ohun idiwọ ẹtọ irina laarin awọn ọmọ Afirika mii.

Ẹwẹ, Babandede ni iforukọsilẹ yóò tẹsiwaju lati lee fun awọn arinrinajo lanfani ati forukọ silẹ ki wọn si le gbe ilu wọn.