Yoruba Film: Ẹ wo ohun táwọn òṣèré tíàtà ń sọ nípa Alabi Yellow tó d'olóògbé

Alabi Yellow ati Kunle Afolayan

Oríṣun àwòrán, Google

Àkọlé àwòrán,

Alabi Yellow ati Kunle Afolayan ninu ere Mọkaliki

Lẹyin ti gbajugbaja oṣere Samuel Akinpelu ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Alabi Yellow jade lade laye, ọpọ awọn oṣere ẹgbẹ rẹ lo ti n ṣedaro rẹ.

Kunle Afolayan sọrọ loju opo Instagam rẹ pe, iku Alabi Yellow dun oun gan ni, ṣugbọn oun gbagbọ pe o gbe igbe aye to dara.

Olorin ẹmi Tope Alabi naa ko gbẹyin ninu awọn to n ṣedaro gbajugbaja oṣere yii nigba to fi sita pe "Sun re o."

Fathia Balogun naa dagbere fun Samuel Akinpelu pe "Sun re o, Alabi Yellow."

Yomi Fabiyi ko gbẹyin nigba to fi si sita lati ki Alabi Yellow pe o di gbere.

Oju opo Instagram rẹ ni Yomi ti sọ pe "Sun re o Pa Alabi Yellow, ẹ ti sa ipa tiyin."

Àkọlé fídíò,

Ǹkan tí ẹ̀mí mímọ́ fi hàn mí kí n tó bẹ̀rẹ̀ orin ìfèdèfọ̀ rèé- Testimony Jaga

Lara awọn to n ṣedaro ẹni ire to lọ naa ni Damilola Ogunsi, ti wọn jọ kopa ninu ere "Mokalik," o ni eeyan daadaa ni Alabi Yellow.

Yatọ si awọn oṣere tiata atawọn olorin ẹmi bi Tope Alabi, ọpọ awọn ololufẹ Alabi Yellow lo n kii pe odigbose lori itakun agbaye.

Ailera ti n ba Alabi Yellow finra fun igba diẹ ki o to wa di pe ọlọjọ de.

Lọ́jọ́ tí Alabi Yellow dágbére f'áyé

Ó di gbéré! Òṣèré Alabi Yellow re'bi àgbà ń rè

Ikede jade pe gbajugbaja oṣere Samuel Akinpelu ti gbogbo eniyan mọ si alabi Yellow ti jẹ eleduwa nipe.

Akinpelu jẹ oṣere ti awọn eeyan ko lee gbagbe fun iru ipa to maa n ko ninu ere sinima agbelewo lorileede Naijiria.

Nigba ti BBC Yoruba kan si Aarẹ ẹgbẹ awọn oṣere,TAMPAN, Bolaji Amusan, Mr Latin lo fidi ọrọ naa mulẹ to si ni adanu nla ni iku Alabi Yellow jẹ lagbo oṣere

Nile rẹ to wa ni Ikorodu ni Alabi Yellow dakẹ si lowurọ ọjọ Aiku lẹyin aisan to ti fi igba diẹ de mọlẹ.

Oríṣun àwòrán, Instagram/alabiyellow

Latin ṣalaye pe oun ti ni ki Alaga ẹgbẹ TAMPAN to wa ni Ikorodu lọ yọju si mọlẹbi oloogbe.

Sinima to kopa kẹyin ninu rẹ ni mọkaliki ti Kunle Afolayan dari rẹ.

Ailera ti n ba Alabi Yellow finra fun igba diẹ ki o to wa di pe ọlọjọ de lowurọ ọjọ Aiku.