Nigeria Police: Ọlọ̀pàá gbẹ̀mí akẹgbẹ́ rẹ̀ àti t'ara rẹ̀

Ọlọpaa Naijiria Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọga ọlọpaa ọhun jade lati inu ọfiisi lati bere ohun to ṣẹlẹ, lo ba tun yin ọga naa nibọn

Rogbodiyan bẹ silẹ nilu Abuja nigba ti ọlọpaa kan, John Markus yinbọn pa akẹgbẹ rẹ, to si tun yinbọn pa ara rẹ lẹyin naa.

Iṣẹlẹ naa waye ni kutukutu ni agọ ọlọpaa to wa ni agbegbe Dutse, ti ọlọpaa mii si ṣeṣe.

Kọmiṣona ajọ ọlọpaa nilu Abuja, ọgbẹni Bala Ciroma fi di ọrọ naa mulẹ fun awọn oniroyin.

O ṣalaye pe iṣẹlẹ ọhun waye ni igba ti Marcus wa lẹnu iṣẹ gẹgẹ bi adena agọ ọhun yinbọn soke.

Wọn ni akẹgbẹ re, kọpura Mathew Akubo bawi, lẹyin eyi lo yin nibọn fun lagbari lẹsẹ kan naa.

Ko pẹ si ni ọkan lara awọn ọga rẹ, Abdullahi Ovanu jade lati inu ọfiisi lati bere ohun to ṣẹlẹ, lo ba tun yin ọga naa nibọn.

Lẹyin iṣẹju diẹ sii ni o ki ibọn ọhun sẹnu, to si dana si ara rẹ.

Ọga rẹ n gba itoju lọwọ nile iwosan, ṣugbọn wọn ti gbe oku rẹ lọ si ile igbokupamọsi to wa ni ile iwosan Kubwa, ni Abuja.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionǸkan tí ẹ̀mí mímọ́ fi hàn mí kí n tó bẹ̀rẹ̀ orin ìfèdèfọ̀ rèé- Testimony Jaga