#China_kills_Muslims: Àwọn èèyàn bọ́ sórí Twitter lórí ìfìyàjẹ musulumi lọ́wọ́ọ China

Awọn obinrin Uighur n ṣe iwọde lori biijọba China ti ṣe fi awọn mọlẹbi wọn si ahamọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lẹnu ọjọ mẹta yii, ẹnu ti n kun orileede China lori ẹsun pe wọn n fiya jẹ awọn ẹya orileede rẹ kan ti ọpọ wọn jẹ musulumi.

Ni agbegbe Xinjiang ni iwaadi igbimọ ajọ isọkan agbaye ti ni o fẹẹ to miliọnu kan musulumi ẹya Uyghur ti ijọba China sọ si ahamọ nibi ti wọn ti n fipa yi wọn lọkan pada.

Iroyin yii ati awọn fọnran fidio to fi mọ bawọn eekan lawujọ ti ṣe n bẹnu atẹ lu China ti mu kawọn eeyan gba oju opo Twitter kan lati fi ẹhonu han si iwa ti China n hu yii.

#China_kills_Muslims ni o n leke ninu ọrọ to n ja rain-rain ni Naijiria loju opo Twitter.

Laipẹ yi ni gbajugbaja agbabọọlu ẹgbẹ Arsenal Mesut Ozil fi ọrọ sita loju opo Twitter rẹ nibi to ti ba awọn Musulumi Uyghur China kẹdun ijiya ti wọn fi n jẹ wọn.

Ọrọ rẹ yi mu ki ileeṣẹ amohunmaworan China fagile ṣiṣe afihan ifẹsẹwọnṣẹ ẹgbẹ Arsenal ni China.

Amọ ṣa, ọrọ Ozil ṣafikun bi awọn eeyan ti ṣe mọ si nipa ijiya awọn musulumi Uyghur tawọn kan si kan sara si fun bi o ti ṣe bawọn kẹdun.

Toun ti gbogbo nkan tawọn eeyan n sọ yii, orileede China faake kọri ni pe ko si ootọ ninu ẹsun pe awọn n fi iya jẹ awọn ẹya musulumi Uyghur.

Awọn ajafẹtọmọniyan ti n ke gbajare si ajọ isọkan agbaye lati gbe igbeṣẹ ijiya to tọ lori China ki wọn ba le dẹkun ijiya awọn Uyghur wọnyii.

Lara awọn ti o wọde fawọn Uyghur la ti ri awọn oluwọde Hong Kong ti wọn ṣapejuwe ijiya tawọn n ri lọwọ ijọba China gẹgẹ bi iru eleyi ti China fi n jẹ awọn musulumi Uyghur.

Aworan ree to ṣe afihan ibi tawọn eeyan ti n ṣe iwọde idaro pẹlu awọn musulumi Uyghur China.