CBN mu adínku ba iye owó sísan lór''i lílo ATM ni Nàíjìrìà

Ami idanimọ Banki apapọ orilẹede Naijiria

Oríṣun àwòrán, Central Bank of Nigeria

Àkọlé àwòrán,

Banki apapọ orilẹede Naijiria lo n se isakoso eto ọrọ owo Naijiria

Ile ifowopamọ apapọ Naijiria CBN ti kede iyipada iye tawọn eeyan yoo ma san lori ifoworanṣẹ tabi gbigba owo lakoto wọn lẹnu ẹrọ ATM.

Naira marundinlogoji ni awọn ile ifowopamọ n gba tẹlẹ amọ bayi wọn yoo ma gba naira márùndínláàdọ́rin lọwọ awọn eeyan.

Ikede iyipada yi ti banki agba fi sita lọjọ Aiku loju opo Twitter wọn ṣalaye iye tawọn eeyan yoo san lati ṣe idunadura lori ẹrọ ATM tabi lohu opo ayelujara taa mọ si Internet Banking.

Nipataki ninu iyipada yi, bi eeyan ba ti fi kaadi ATM rẹ gba owo niule ifowopamọ mi ju ẹmẹẹta lọ loṣu eleyi to ba tẹle yoo san naira marundinlogoji dipo naira arundinlaadọrin ti wọn n san tẹlẹ.

Bi o ba jẹ loju opo ayelujara ni,iye owo ti eeyan yoo san lọ bayi:

  • Ti owo ba kere ju 5,000=N10
  • Laarin 5,000-N50000=N25
  • Ti o ba kọja N50,000=N50
  • Owo atunṣe kaadi ATM N50 laarin oṣu mẹta mẹta fun Savings
  • Awọn to n lo Current Account ko ni san owo

Bi awọn eeyan kan ṣe n kan sara siwọn fun igbesẹ yi, lawọn mii ni ki CBN wa nkan ṣe si owo ẹrọ POS tawọn ile epo ma n gba lori lilo POS lọdọ wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: