CAN: Ẹgbẹ́ ọmọlẹ́yìn Krístì ni ó dáa bí Amẹ́ríkà ṣé ń ṣọ́ Nàìjíríà lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀

Ilé ìjọsìn

Oríṣun àwòrán, Dan Kitwood

Ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristi lorileede Naijiria CAN ti kan sara si orileede Amẹrika pẹlu bo ti ṣe gb'orukọ Naijiria jade lara awọn orileede to n tẹ ẹtọ ẹsin eeyan mọlẹ.

Ninu atẹjade kan ti Pasitọ Adebayo Oladeji fi sita lorukọ aarẹ ẹgbẹ naa lọjọ Aiku, CAN ni wọn ti sọrọ yii.

CAN ni toun ti bi ko ṣe dun mọ awọn ninu pe Naijiria n gba orukọ ti ko daa, igbesẹ yii ṣafihan pe awọn ara ita naa mọ ohun toju awọn Kristẹni n ri ni Naijiria.

Ṣaaju ni Minisita feto Iroyin Naijiria Lai Mohammed ti fi atẹjade tirẹ sita to fi tako oun ti Amẹrika sọ.

Lai Mohammed ni awọn oloṣelu alatako lo n gbiyanju lati sọ Naijiria lẹnu pẹlu bi wọn ti ṣe n wọ aṣọ ẹsin fun gbogbo aawọ to n ṣẹlẹ ni Naijiria.

Ninu ọrọ CAN wọn tọka si bi aarẹ Buhari ti ṣe n fa ori apa kan da apa ka si paapa julọ pẹlu iyansipo awọn to n dari eto aabo Naijiria.

Bakanna ni CAN sọ pe awọn Kristẹni n koju inira lọwọ awọn Boko Haram ati darandaran Fulani ni awọn ipinlẹ bii Kaduna, Benue, Plateau Adama ati Taraba.

Wọn wa rọ aarẹ Buhari lati ṣe atunṣe to yẹ lati ṣe deede ati dọgba n dọgba laarin awọn eeyan Naijiria lai fi ti ẹya tabi ẹsin ṣe.