Christmas: Nkan márùn ún tóo lè fi jàjà bọ́ lọ́wọ́ ìjákulẹ̀ téélọ̀ rẹ

Aworan ranṣọ ranṣọ
Àkọlé àwòrán,

Nkan márùn ún tóo lè fi jàjà bọ́ lọ́wọ́ ìjákulẹ̀ téélọ̀ rẹ

Asiko ọdun Keresimesi ku dẹdẹ ti ipalẹmọ si ti n lọ ni yanturu.

Pupọ eeyan lo ti ra adiyẹ ti yoo pa, wọn ti ṣe ra epo sọkọ fun irinajo, wọn ti ra ẹbun ti wọn yoo fun ẹbi ara ati ọrẹ.

Koda, eronja jọlọọfu ti wọn yoo se lọjọ ọdun ti wa ni ṣẹpẹ. Gbogbo nkan lo ti wa ayafi nkan ẹyọkan ti o ku aṣọ ti wọn yoo fi ṣe ọdun.

Oríṣun àwòrán, @EarlJoey_.

Àkọlé àwòrán,

Nkan márùn ún tóo lè fi jàjà bọ́ lọ́wọ́ ìjákulẹ̀ téélọ̀ rẹ

Ẹ pe ransọ-ransọ, o kọ, ko gbe ipe, wọn ti de sọọbu rẹ laimọye igba ṣugbọn aṣọ to loun yoo pari ni ijọ keji ko tii pari.

Ṣe ẹ ti ni iriri iru ijakulẹ yi lọwọ teeọ yin ri abi?

Bawo lo ṣe ri lara, ki si ni ohun to yẹ ki ẹ ṣe lati dena irufẹ iṣẹlẹ bẹẹ.

Alaye awọn nkan marun un tẹ le ṣe lati fi kọ ijakule lọwọ telọ yin ree.

Àkọlé fídíò,

Ohun mẹ́jọ tóo ní láti mọ̀ bí o bá fẹ́ lọ ilé ọdun

Ma wulẹ ran aṣọ ọdun

Ootọ ọrọ a ma jọ isọkusọ ṣugbọn ohun ti Idris Oluwaṣeun to ti ni iru iriri yi sọ fun BBC ni pe ki eeyan ma ran aṣọ ọdun lo ṣe ogun pe awọn telọ ko ni ja ireti rẹ kulẹ.

O ṣalaye pe o ṣoro ki ransọ-ranṣọ to ja ireti eeyan kulẹ ti ko ba ni aṣọ ti eeyan gbe fun un.

Ohun ti eleyi tumọ si ni ṣoki ni pe ki eeyan ra aṣọ ti wọn ba ti ran kalẹ tabi ki o kuku ma gbe aṣọ fun telọ rara.

Àkọlé àwòrán,

Ko yẹ ki o tun ri ijakulẹ Teelọ lọdun yii

Tete gbe aṣọ lọ ile teelọ

Bo tilẹ jẹ wi pe awọn teelọ ko mọ pe eeyan tete gbe aṣọ wa, o san ki eeyan tete gbe e lọ si ọdọ wọn ju ki eeyan pẹ gbee lọ.

Abdulwaheed Kareem to jẹ ransọ ransọ sọ fun BBC Yoruba pe lọpọ igba kii ṣe ẹbi awọn ni pe awọn kii le pari aṣọ ọdun awọn onibara awọn lasiko.

Àkọlé àwòrán,

Kii ṣe gbogbo igba la fi ma n jẹbi aitete ran aṣọ ọdun awọn eeyan

O ni pupọ ''eeyan ni kii tete gbe aṣọ wa ti wọn a si ma reti pe ki a pitu pari aṣọ ti wọn ko tete gbe wa''

Ni igba wo wa lasiko to ya lati gbne aṣọ dun lọ fun ranṣọ-ranṣọ?

Abdulwaheed ni ''Bi ẹ ba yara gbe aṣọ yin lọ bi oṣu kan tabi meji ki ọdun to de,o ṣeeṣe ki ijakulẹ ma waye.''

Rii wi pe o ni aṣọ miiran kalẹ ti ijakulẹ ba waye

Teelọ ti ṣe bi o ti ṣe wu u pẹlu pe ko pari aṣọ ti o fẹ wọ lọjọ ọdun. Ko si ṣiṣe, ko si aiṣe, ohun to ku ni ki o wa aṣọ miiran lati wọ.

Ki ọrọ to di bayii, rii wi pe o ti fi aṣọ too ni niile tẹlẹ pamọ de ijakulẹ.

Fọ aṣọ rẹ, fi ẹgẹ si i, lọ ọ ko jọju ki o si ka a pamọ. Bi ijakulẹ ba waye, ṣa asọ rẹ sara ki o si maa ba faaji ọdun rẹ lọ.

Oríṣun àwòrán, @AMAAWARDS

Kun fun adura

Bẹẹni o. Ko si ohun ti adura ko le ṣe. Koda teelọ to fẹ ran aṣọ ọdun, ọrọ rẹ gba adura.

Kete ti o ba ti gbe aṣọ fun un ni ko ti ko si adura ni kikankikan.

Oríṣun àwòrán, Ahmed Ambali

Àkọlé àwòrán,

Ọlamide

Tẹnumọ ninu adura rẹ pe ki ẹmi idaniduro ma ṣe ko si teelọ rẹ ninu.

Bi adura rẹ ba gba, ọrọ bu ṣe.

Ti telọ rẹ ba bere owo''ẹxpress'' waa fun un ki o to bẹrẹ si ni sọ awawi

Lọpọ igba awọn telọ ma n sọ pe iṣẹ pọ lọwọ awọn ṣugbọn wọn ko ni tori rẹ ma gba iṣẹ sii lasiko ọdun.

Ṣe o ri awọn aṣọ ti wọn gba lọdun ku la ti wọn si pari rẹ fawọn to nii, wọn san owo ju tirẹ lọ ni.

Nitori eyi, bi telọ rẹ ba ni ki o mu owo ẹxpress wa ki ohun ba le tete pari aṣọ rẹ, ti o ba ni owo naa, yara fun un.

Ọna kan ree lati fi dena ijakulẹ lọwọ telọ lasiko ọdun.

Gbogbo awọn nkan ti a ka kalẹ yi kii ṣe aridaju ọna kan gboogi lati le dena ijakulẹ.

Imọran ni wọn jẹ ti omii ninu wọn le ṣiṣẹ ti omiran si le ma kopa kankan lara teelọ rẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ọdọọdun ni gbogbo ẹlẹsin Kristẹni lagbaye ma n parapọ lati se ayẹyẹ Ọjọ ibi Jesu Kristi.

Bi o ba ni ajọsepọ to ti pọ pẹlu telọ rẹ bi yoo ba ja ọ kulẹ, ko ni ro o wo lẹẹmeji.

Ayọ ati aṣọ ọdun wa la o fi ṣe keresi yio o!

Àkọlé fídíò,

Christmas:Ṣé ẹ ti ra fìlà ọdún?