Akure Kidnap: Ilé ẹjọ́ fi Wòlíì Alfa sí ẹ̀wọn ọjọ́ mọ́kànlelógún

Àkọlé fídíò,

Sotitobire Church: Ilé ẹjọ́ fi Wòlíì Alfa sí ẹ̀wọn ọjọ́ mọ́kànlelógún

Bayii awọn agbofinro ipinlẹ Ondo ti foju awọn ara ìlú ti wọn kọlu ile ijọsin naa hanỌlọ́pàá Akurẹ kó àwọn ará ìlú tí wọ́n ni wọ́n jí ẹrù Pásítọ̀ Sọ titobi rẹ kó lọ sílé ẹjọ́

Wọn ko wọn wa sile ẹjọ ni Oke Ẹda ni Akurẹ nibi ti wọn ti fẹsun kan awọn mẹtala naa pe wọn pa ọlopaa, wọn ji ohun ini Wolii Sotitobire ko nile ijọsin ti wọn dana sun ati awọn ẹsun miran Ọlọ́pàá Akurẹ kó àwọn ará ìlú tí wọ́n ni wọ́n jí ẹrù Pásítọ̀ Sọ titobi rẹ kó lọ sílé ẹjọ́

Ọgbà ẹ̀wọ̀n ní Pásítọ̀ ìjọ Sotitobire yóò ti ṣe Kérésì

Lowurọ oni ni ijọba ipinlẹ Ondo gbe Pasitọ Alfa Babatunde tii ṣe oludasilẹ ijọ Sotitobire ni Ondo lọ si ile ẹjọ.

Lẹyin ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun to waye nile ẹjọ, adajọ ni ki wọn sọ Pasitọ naa si ẹwọn ọjọ mọkanlelogun gbako titi wọn yoo fi pari iwadii.

Fun idi eyi, ile ẹjọ ti sun igbẹjọ si ọjọ kẹtadinlogun oṣu kinni ọdun 2020.

Ẹsẹ̀ ko gbero ninu ile ati ita ọgba ile ẹjọ Oke Eda niluu Akurẹ nibi ti ijọba gbe e lọ.

Ṣe ni awn ero to wa woran kawọ mori nigba ti wọn ri i to jade sita lati inu ile ẹjọ tori nigba ti wọn gbe e wọle, awọn oṣiṣẹ DSS yi i ka wọn ko si jẹ ki ẹnikẹni ribi sunmọ ọ.

Ọkan lara awọn agbẹjọro to wa nibi igbẹjọ naa sọ pe ni ilana ofin, ko tii si aridaju kankan ti wọn fi lelẹ pe o jẹbi ẹsun ti wn fi kan an.

Ijọba ipinlẹ Ondo lo gbe pasitọ ijọ Sọtitobire Miracle Centre, Woli Alfa Babatunde lọ ile ẹjọ fun ẹsun ijọmọgbe.

Alfa Babatunde wa nile ẹjọ Oke Eda, to wa nilu Akure lọwọ bi a ṣe n kọ iroyin yii.

Pasitọ naa ati awọn meje miiran ni ijọba lo foju bale ẹjọ lonii.

Lara ẹsun ti wọn fi kan woli naa ati awọn eeyan rẹ ni iditẹ lati ji ọmọ gbe ati ẹsun jiji ọmọ gbe.

Gẹgẹ bi iwe ẹsun naa ṣe sọ ọ, lara awọn eeyan ti ijọba pe lẹjọ ọhun ti na papa bora.

Nigba ti akọroyin wa fi ọrọ wa agbẹjọro rẹ lẹnu wo, o ṣalaye pe bi onibara oun ko ba ṣ si ofin, wọn yoo fi silẹ. Ṣugbọn bi wọ́n ba rii pe o jẹbi, oun gan gba pe ki wọn fi jofin.

"Awa gan n fẹ idajọ to tọ", lọrọ ti agbẹjọro rẹ sọ.

Àkọlé fídíò,

Akure Kidnap: Àwọn abiyamọ fẹ̀hónúhàn lórí ọmọ tí wan jígbé nílé ìjọsìn Akurẹ