Christmas: Ṣé à ń lọ s'ílé ọ̀dún pọndandan? Ohun tó yẹ kóo mọ̀ rèé- Olatunbosun Bolarinwa

Christmas: Ṣé à ń lọ s'ílé ọ̀dún pọndandan? Ohun tó yẹ kóo mọ̀ rèé- Olatunbosun Bolarinwa

'Má lọ wọ sọọ̀lẹ̀ lásìkò ọdún yìí o! Gbọ́ àwọn ìkìlọ̀ yìí'

Ẹ gbọ́ kìí ṣe gbogbo ìrìnàjò ló pọn dandan.

Bi o ba wa pọn dandan fun ẹ paapaa lasiko ọdun yii, wo fọnran to wa ninu iroyin yii fun ẹkunrẹrẹ alaye awọn koko pataki to yẹ ki o mọ koo to gbera irinajo.

Ni kanmọ kanmọ, Ogbeni Olatunbosun Bolarinwa to jẹ onimọ nipa eto aabo nilẹ Naijiria fa awọn eeyan leti bi wọn ba ti rii pe afi dandan ki wọn rinrinajo.

Asiko pọpọṣinṣin ọdun Keresi mu ki awọn eeyan gbagbọ pe o ma n mu ọpọ ewu dani. Nitorinaa onimọ Bolarinwa ni:

  • Rin irinajo rẹ ni kiakia
  • Ma rinrin oru
  • Lọ wọ ọkọ ni ibudokọ, ma wọ sọọlẹ lasiko ọdun
  • Wo ihuwasi dẹrẹba to n wa ọkọ rẹ.

5. Gba nọmba aladugbo rẹ ki o si fun wọn ni tirẹ.

6. Ni nọmba ọga ọlọpaa adugbo rẹ tabi nọmba ti ijọba gbe kalẹ fun eto abo ladugbo rẹ. Eyi ko nilo owo lati pe.

7. Ibi ti o dagbere ni ki o lọ...

Ẹwẹ, onimọ nipa aabo, Bolarinwa tun sọ awọn ikilọ pato fun awọn obinrin tori iṣẹda wọn.