Quilox: Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ti Quilox, ilé ijó Shina Peller pa nítorí ariwo

Awọn oṣiṣẹ LASEPA niwaju ile ijo Quilox

Oríṣun àwòrán, @Mr_JAGs

Ijọba ipinlẹ Eko ni awọn ti sọ agadagodo si ẹnu ọna gbajumọ ile ijo Quilox lori ẹsun pe o n da ariwo pa ilu ati sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ.

Amugbalẹgbẹ fun gomina ipinlẹ Eko lori ọrọ ayelujara, Jubril Gawat kede loju opo twitter pe ajọ idaboobo bo ayika lo ti ile ijo Quilox to wa lagbegbe Victoria island.

Ni ọsan ọjọ aje ni iroyin bọ sita pe Ileeṣẹ ọlọpaa ti fi panpẹ ọba mu Aṣofin Shina Abiọla to ni ile ijo naa.

Aṣofin Shina Abiọla lo n ṣoju fun ẹkun apapọ Iseyin/Itesiwaju/Kajola/Iwajowa nile aṣofin apapọ.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ọwọ ofin baa pẹlu awọn eeyan marun ti wọn funra si pe wọn jẹ janduku

Aṣofin Abiọla ti ọpọ mọ si Shina Peller to tun ni ile igbafẹ kan nilu Eko lawọn ọlọpaa ni mimu ti wọn mu u ko ṣẹyin rugudu kan to waye nile ijo naa lẹyin ọjọ diẹ to kede nile aṣofin pe oun ti yọwọ ninu akoso ile ijo yii.

Ileeṣẹ ọlọpaa fi ẹsun kan an pe o ko awọn janduku bii aadọta jọ lati kọlu agọ ọẹọpaa kan ni Maroko lẹyin tawọn ọlọpaa lati agọ naa lọ palẹ sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ tawọn onibara ile ijo rẹ da silẹ mọ.

Àkọlé fídíò,

Ohun mẹ́jọ tóo ní láti mọ̀ bí o bá fẹ́ lọ ilé ọdun

Alukoro ileeṣẹ ọẹọpaa ipinlẹ Eko, Elkana Bala ni awọn ni lati ko ọlọpaa kun awọn to wa ni agọ naa ni ki wọn to lee ja ajabọ lọwọ awọn tọọgi ti wọn ni Shina Peller ko lọ sibẹ lati fi tipatipa ko awọn ọkọ to wa lagọ naa kuro.

Amọṣa, atẹjade kan lati ọdọ agbẹnusọ fun aṣofin Shina Abiọla ni ṣe ni aṣofin naa lọ si agọ ọlọpaa lati beeli awọn onibara ile ijo rẹ kan to wa nibẹ ti wọn ni wọn gbe ọkọ di oju popo lasiko eto kan ni ile ijo naa