Sowore: Nítorí ìròyìn Sahara Reporters, Adájọ́ ní òun kò leè gbọ́ ẹjọ́ Sowore

Sowore ni ile ẹjọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Adajọ kan ni ile ẹjọ giga apapọ nilu Abuja ti ys ọwọ rẹ kuro ninu ẹjọ Ọmọyẹele Soworẹ to wa lahamọ ajọ agbofinro DSS bayii.

Ko si si idi meji ti adajọ Mohammed la kalẹ ju wi pe, ni igba kan ri sẹyin, Ọmọyẹele Soworẹ to ni ileeṣẹ itẹwe iroyin Sahara Reporters ti fi ẹsun kan oun ri nigba meji ọtọọtọ pe oun gba owo lori awọn nnkankan lati da kẹkẹ ẹjọ nu.

Soworẹ tọ ile ẹjọ giga apapọ lọ lati gba aṣẹ pe ki ajọ DSS ye tẹ ẹtọ ọmọniyan oun mọlẹ ati pe ki ile ẹjọ paṣẹ ki DSS san ẹẹdẹgbẹta miliọnu naira gẹgẹ bii owo gba maa binu fun oun.

Adajọ naa ni ọpọlọpẹ awọn agbẹjọro agba meji kan lo yọ oun ninu ọfin ẹsun naa.

Àkọlé fídíò,

Oluwo Divorce: ko si ẹni ti kò mọ pé ọmọ ilẹ̀ òkèrè ni mó fi ṣe aya

Onidajọ Mohammed ni idajọ ẹjọ naa lee fi si ibikibi. O ni ti idajọ oun ko ba gbe Soworẹ, o lee ro wi pe oun fi gba ẹsan iroyin ti iwe iroyin rẹ gbe jade nipa oun ni.

Amọṣa agbẹjọro fun Soworẹ, Amofin Fẹmi Falana, SAN ṣalaye pe oun ko mọ si iroyin ti adajọ n sọrọ rẹ naa. O ni nigba to ti ri bayii, ko si oun meji ju pe ki adajọ yọ ọwọ rẹ kuro ninu ẹjọ naa ni.

Agbẹjọro fun DSS, Godwin Agbadua si faramọ eyi.