Deji Adeyanju: Àwọn olólùfẹ́ Ààrẹ Buhari kọlu Deji Adeyanju àtàwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ tó wọ́de l'Abuja

Awọn oluwọde pẹlu akọle loriṣiriṣi

Oríṣun àwòrán, @SaharaReporters

Awọn ololufẹ ijọba aarẹ Buhari kan to n wọde lorilẹede Naijiria ti kọlu awọn aṣiwaju ẹgbẹ ajafẹtọ nibi ti wọn ti n ṣe iwọde lati pe fun itusilẹ awọn ti ijọba fi si ahamọ 'lọna aitọ'

Ọkan lara awọn aṣaaju ẹgbẹ naa ti di ero ileewosan nilu Abuja nibiti o ti n gba itọju fun ọgbẹ ara rẹ.

Ni iwaju ileṣẹ ajafẹtọ araalu lorilẹede Naijiria, NHRC korajọ pọ si lati ke si ijsba orilẹede Naijiria lati maa bọwọ fun ofin ki wọn si tu awọn ajafẹtọ ti wọn de si igbekun silẹ.

Eyi ni igba akọkọ ti awọn ẹgbẹ to n ṣatilẹyin fun ijọba yoo gbe ina woju awọn oluwọde to n tako ijọba ni gbangba.

Oríṣun àwòrán, @SaharaReporters

Awọn eeyan ọhun ti wọn to bii ọgọta niye gbe patako ti wọn kọ oriṣiriṣi ọrọ oriyin fun aarẹ Buhari si.

Nṣe lawọn agbofinro si ko oju sẹgbẹ l;asiko ti awọn eeyan naa fi sare si Ọgbẹni Deji Adeyanju to jẹ ọkan lara awọn aṣiwaju ẹgbẹ to n tako ijọba naa.

Oríṣun àwòrán, @SaharaReporters

Lilu bii bara ni wọn luu pẹlu okuta ati igi ki awọn ọẹọpaa to ronupiwada wa gbaa silẹ. Ileewosan lo gba Ọgbẹni Deji Adeyanju silẹ .

Ohun ti awọn ẹgbẹ ajafẹtọ naa n ja fun ni itusilẹ awọn ti ijọba gbe sọ si ẹwọn lsna ti ko bofinmu ati 'didawọ awọn eeyan ti wọn fina mọ nitori iha oṣelu wọn' duro