Falana àti Garba Shehu takurọ́sọ lórí ẹsùn pé Buhari fẹ́ dupò fún sáà kẹta

Garba Shehu ati Femi Falana
Àkọlé àwòrán,

Falana àti Garba Shehu takurọ́sọ lórí ẹsùn pé Buhari fẹ́ dupò fún sáà kẹta

Agbẹnusọ aarẹ Buhari, Garba Shehu ati ilumọọka agbẹjọro Femi Falana ti n gbe'na woju ara wọn lori ọrọ pe aarẹ Muhammadu Buhari yoo ṣe tabi ko ni ṣe saa kẹta.

Itakurọsọ naa to waye loju opo Twitter ti mu ki awọn eeyan bẹrẹ si ni yan ẹni ti wọn yoo gbe lẹyin ninu awọn mejeeji.

Lọjọ Aje ni Garba Shehu fi ọrọ kan sita to fi tako ọrọ to ni awọn kan n gbee kaakiri ori ayelujara pe aarẹ Buhari fẹ ṣe saa kẹta.

Ninu awọn ti Garba darukọ pe o n gbe iroyin ofege yi ka ni Femi Falana ti o ṣe apejuwe rẹ gẹgẹ bi oludije alatako to fidirẹmi ninu idibo gomina l'Ekiti lọdun diẹ sẹyin.

Laipẹ yi ni Femi Falana sọ ninu ifọrọwero kan pẹlu BBC pe oun ni ẹri pe Aarẹ Buhari ni erongba lati dije sipo aarẹ fun igba kẹta.

Garba sọ pe ko si ohun to le ṣẹlẹ ti yoo mu ki Aarẹ Buhari du ipo fun saa kẹta.

Shehu tẹnumọ ọ pe Aarẹ Buhari ko ran ẹnikẹni lati gbe igba ipolongo saa kẹta fun oun rara.

Femi Falana ko ti i fesi si ọrọ ti Garba Shehu sọ yi ṣugbọn awọn alatilẹyin Falana kan ti n fun Shehu lesi pada loju opo Twitter.

Àkọlé fídíò,

Ondo disability day: Ijọba ẹ gbà wá ní ariwo tí àkàndá ẹ̀dá ń pa

Bẹẹ lawọn to n gbe lẹyin Garba Shehu naa n dawọn lohun lori ayelujara pe:

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Mobile App: Àsìkò tó wu àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ni olùkọ́ máa jáde wa kọ́ wọn láti inú fóònù wọn