Bi adẹrinpoṣonu Stephen Sotonwa ṣé kàgbákò ikú nínú ìjàmbá ọkọ̀ ní Ondo nìyìí

Aworan Stephen Sotonwa

Oríṣun àwòrán, Google

Àkọlé àwòrán,

Bi adẹrinpoṣonu Stephen Sotonwa ṣé kàgbákò ikú nínú ìjàmbá ọkọ̀ ní Ondo nìyìí

Kaakiri loju opo ayelujara ọrọ idaro lawọn ẹbi ati ọrẹ fi n ranti rẹ.

Ta ni 'Sweet Steve' adẹ́rìnpòṣònú tí àwọn èèyàn n ṣé ìdárò rẹ̀?

Olufemi Stephen Sotonwa ti inagijẹ rẹ a si ma jẹ 'Sweet Steve' dagbere faye lọjọ Aiku ninu ijamba ọkọ kan to waye ni oju ọna Akure si Ile Oluji ni ipinlẹ Ondo

Yatọ si pe o jẹ adẹrinposonu, Sweet Steve a si tun maa ṣe atọkun eto ati adari ayẹyẹ eleyi ti oloyinbo n pe ni MC.

O ṣiṣẹ pẹlu Orange FM 94.5 ni Akure nibi to ti ṣe atọkun eto.

Iku rẹ ba awọn ti wọn mọ lojiji paapaa julọ laarin awọn akẹgbẹ rẹ lagbo sọrọsọrọ .

Woli Arole, Gbenga Adeyinka ati Omo Baba wa lara awọn to ba mọlẹbi rẹ kẹdun.

Àkọlé fídíò,

Christmas:Ṣé ẹ ti ra fìlà ọdún?

Koda Kọmiṣọnna feto ibaraẹnisọrọ nipinlẹ Ondo Donald Ojogo fi ọrọ ikẹdun sita to si ṣapejuwe Stephen gẹgẹ bi ọdọ to jẹ awokọṣe fawọn akẹgbẹ rẹ.

Àkọlé fídíò,

Ohun mẹ́jọ tóo ní láti mọ̀ bí o bá fẹ́ lọ ilé ọdun