Bánkì tó bá kọ láti tẹlé ìlànà CBN tuntun, ₦2m ní yóò fí gbára

CBN

Oríṣun àwòrán, @CBN

Ile ifowopamọ apapọ lorile-ede Naijiria CBN ti fi ikilọ sita fawọn ile ifowopamọ to ba kọti ikun si ilana tuntun ti wọn gbe jade.

Ilana yii da lori owo ti ara ilu yoo ma san ti wọn ba fi owo ranṣẹ tabi gba owo ni banki.

Ikede yi ti wọn fi sita loju opo Twitter wọn waye lẹyin eleyi ti wn sọ saaju pe iyipada ti de ba iye owo ti banki yoo ma gba lọwọ ẹni to ba gba owo nidi ATM ati loju opo ayelujara.

CBN lawọn n kede awọn ilana tuntun yi gẹgẹ bi ọna lati daabo bo awọn onibara ile ifowopamọ Naijiria

Àkọlé fídíò,

Àwọn aránṣọ yarí pé gbogbo ẹ̀bi kìí ṣe tàwọn, díẹ̀ wà lọ́wọ́ àwọn oníìbárà náà

Bakan naa ni ile ifowopamọ agba naa sọ pe awọn ile ifowopamọ ni lati ṣe akọsilẹ aroye tawọn onibara wọn ba mu wa bi bẹẹkọ wọn yoo fara gba owo itanra miliọnu naira kan.

Wọn tun ni aadọta naira ti awọn onibara n san lori rira ọja pẹlu kaadi POS ni ko yẹ ko ri bẹẹ.

CBN awọn olokowo ati ileeṣẹ to n gba owo naa lọwọ onibara lo yẹ ki wọn maa san owo naa.

Gbogbo awọn igbesẹ yii ni wọn ni yoo mu ki awọn onibara le gbadun idunadura pẹlu ile ifowopamọ wọn.

Àkọlé fídíò,

Christmas:Ṣé ẹ ti ra fìlà ọdún?

Ko yẹ ki onibara san ₦50 lori pe o san owo pẹlu POS

Ẹwẹ, CBN ti ṣalaye pe owo aadọta Naira tawọn ile itaja paapa julọ ile epo n gba lọwọ alabara wọn to ba lo ẹrọ isanwo POS ko tọna.

Wọn ni ile ontaja to n ta ọja falabara lo yẹ ki wọn san owo naa.

Lori eto kan to waye lori ile iṣẹ amohunmaworan Channels TV ni ẹkunrẹrẹ alaye yi ti waye.

Alaye naa ko ṣẹyin ibeere tawọn eeyan n beere latari ikede iyipada awọn owo to yẹ ni sisan fẹni to ba lo ẹrọ ATM.

Musa Jimoh to jẹ adari ni ẹka to n mojuto sisan owo ni CBN sọ pe''iwe ta gbe sita nipa pe kawọn oniṣowo ma san owo ko tumọ si pe ki onibara wọn ma san.''

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Musa tẹsiwaju pe''ti iye owo ọja ti ẹ ta ba ti kọja ẹgbẹrun kan naira,ẹyin ti ẹ n taja lẹgbọdọ san''

O ni ohun tawọn ṣalaye fawọn ile ifowopamọ ni pe awọn fẹ ki awọn olutaja tẹle aṣẹ yi ṣugbọn pupọ ninu wọn n pọn dandan fawọn onibara lati san owo naa fun wọn.