Otuoke attack: Ààrẹ Buhari ní àbò wà fún ẹ̀mí ààrẹ́ àná, Goodluck Jonathan

Jonathan ati Buhari

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Aarẹ Buhari ti pe Aarẹ ana, Goodluck Jonatha lori ẹrọ ibanisọrọ lati baa kẹdun lori ikọlu awọn agbebọn to waye ni Otuoke tii ṣe ilu ibinibi rẹ nipinlẹ Bayelsa.

Àkọlé fídíò,

Christmas & Border Closure: ìrẹsì dí góòlù fún Kérésì 2019

Ninu ọrọ ori foonu naa, aarẹ Buhari ko fi bi iṣẹlẹ naa ṣe ba oun ninu jẹ pamọ. O ṣe akawe rẹ gẹgẹ bi iṣẹlẹ ibanujẹ nla ti o si ku diẹ kaa to.

Aarẹ tun kan sara sawọn ṣọja to n ṣọ ile aarẹ Jonathan fun bi wọn ṣe koju ija naa gẹgẹ bi akin. O wa ba awọn ẹbi ọmọ ogun to ṣubu loju ija naa daro.

Àkọlé fídíò,

Parental Guidance: Ọdún méjì ni kí ẹ ti bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ọmọ nípa ìbálòpọ̀

Aarẹ Buhari wa fi da awọn ọmọ orilẹede Naijiria loju pe abo to yẹ n bẹ fun ẹmi aarẹ ana naa ati gbogbo awọn ọmọ orilẹede Naijiria lai yọ ẹni kan silẹ ati pe abo ni yoo tubọ maa jẹ iṣejọba oun logun.

Àkọlé fídíò,

Christmas:Ṣé ẹ ti ra fìlà ọdún?

Ni Ọjọ Iṣẹgun ni iroyin jade sita pe awọn agbebọn kan kọlu ilu Otuoke to jẹ ilu aarẹ ana, Ọmọwe Goodluck Jonathan ti wọn si pa ṣọja kan nibẹ.

Àkọlé fídíò,

Ohun mẹ́jọ tóo ní láti mọ̀ bí o bá fẹ́ lọ ilé ọdun