FRSC: Ọkọ̀ agbépo tó da epo sílẹ̀ fa súnkẹrẹ-fàkẹrẹ ní Eko sí Ibadan

Awọn osisẹ pajawiri wa pẹlu ọkọ epo to n da epo silẹ
Àkọlé àwòrán,

Ọkọ̀ agbépo tó da epo sílẹ̀ fa súnkẹrẹ-fàkẹrẹ ní Eko sí Ibadan

Bi ẹ ba n ririn ajo lowurọ ọjọ ọdun Keresi jade kuro nilu Eko, iroyin yi yẹ ki o ṣeyin lanfaani.

Ajọ ẹṣọ alaabo oju popo ti kede pe ọkọ agbepo kan ti o danu ti ṣe okunfa idiwọ lilọ bibọ ọkọ loju ọna marosẹ Eko si Ibadan.

Ninu atẹjade kan ti Florence Okpe fi sita lorukọ ọga ajọ naa tẹka ipinlẹ Ogun, sọ pe awọn ti bẹrẹ si ni da epo inu rẹ kuro sinu ọkọ mii.

O ni fun idi eyi, awọn arinrinajo ti n koju idiwọ lataari pe sunkẹrẹ fakerẹ ọkọ ti de ba ẹgbẹ opopona mejeeji marose naa.

Àkọlé fídíò,

Ohun mẹ́jọ tóo ní láti mọ̀ bí o bá fẹ́ lọ ilé ọdun

Florence sọ pe ''Ni nkan bi aago marun un kọja iṣẹju mẹwaa ni ọkọ agbepo naa danu lẹba Mowe ''

Ajọ naa wa rọ awọn arinrinajo lati ṣe amulo ọna miran bi i ti Victoria Island- Ajah- Ijebu Ode, ati oju ọna to gba marosẹ Lagos - Ota- Itori - Abeokuta.

Àkọlé fídíò,

Àwọn aránṣọ yarí pé gbogbo ẹ̀bi kìí ṣe tàwọn, díẹ̀ wà lọ́wọ́ àwọn oníìbárà náà

Ninu alaye rẹ ajọ naa ni yoo gba awọn ni asiko diẹ ki wọn to ribi pari eto dida epo inu ọkọ naa pada ati gbigbe kuro ninu koto to ja si.

Àkọlé fídíò,

Christmas:Ṣé ẹ ti ra fìlà ọdún?