Wizkid: 'Ọfẹ ní hug'; Ṣé Wizkid yóò fẹ padà wá kọrin ní Ilorin mọ pẹlú òun tí ojú rẹ rí

Aworan Wizkid
Àkọlé àwòrán,

Wizkid: 'Ọfẹ ní hug

Ilorin Ilu Alimi lo gbori Twitter laarọ yi faa!

Ṣugbọn kii ṣe nitori awọn alufaa onilawani lawọn eeyan ṣe n sọrọ rẹ.

Nitori gbajugbaja olorin takasufẹ Naijiria nii, Wizkid to wa ṣere lọjọ ọdun Keresi, ni wọn ṣe n mu orukọ Ilorin bọ ẹnu

Bi o ko ba si ni agbo ariya naa to waye nile itura Kwara Hotel, jẹ ki a ṣe ofofo ara ọtọ to waye nibẹ fun ọ.

Akọkọ ohun manigbagbe to waye nibẹ ni bi awọn ololufẹ Wizkid kan ti ṣe ja wọ oju agbo ti wọn si n dimọ gidigidi.

Kakiri ori ayelujara ni fọnran fidio ibi tawọn ololufẹ rẹ ti ja wọ oju agbo yi wa.

Ninu fidio naa, a gbọ ti Wizkid sọ fun awọn to n sọọ pe ''ọfẹ ni hug'' ti awọn ololufẹ rẹ si n dimọ bi ẹni pe o fẹ sa mọ wọn lọwọ.

Àkọlé fídíò,

Ǹkan tí ẹ̀mí mímọ́ fi hàn mí kí n tó bẹ̀rẹ̀ orin ìfèdèfọ̀ rèé- Testimony Jaga

Ko jọ bi ija ni wọn fi fa arabinrin kan kuro lọdọ Wizkid tawọn mi si n gbiyanju lati dimọ ọ.

Yatọ si ọrọ bi wọn ti ṣe gun ori itage lọ ba yi, awọn miran ti n ta si Ilorin pe wọn tabuku ba Wizkid nitori wọn gbe aga onike fun un pe ko jọko si.

Lẹnu awọn wọnyii, bi igba pe wọn o yẹ Wizkid si to ni iru iwa yi jẹ

Àkọlé fídíò,

Ohun mẹ́jọ tóo ní láti mọ̀ bí o bá fẹ́ lọ ilé ọdun

Ki wa lawọn ti Ilorin sọ?

Esi tawọn to wa si agbo Wizkid naa ṣebi ẹni mu ibinu wa ti wọn si ni inu awọn dun lo jẹ awọn fi ifẹ han si Wizkid.

Wọn ni awọn o ṣẹṣẹ ma gba alejo awọn eeyan jankan jankan bi Jose Mourinho, Jayz, Falz ati pe ṣebi Wizkid gba owo ki o to wa kọrin nilu Ilorin.

Àkọlé fídíò,

Christmas:Ṣé ẹ ti ra fìlà ọdún?

Wọn ni ki ẹlẹmọṣọ awọn to n bẹnu atẹ lu Ilorin lọ ṣọ ohun ti wọn gbe sọdọ rẹ ki wọn si ma ba ariya jẹ fawọn.

Àkọlé fídíò,

Àwọn aránṣọ yarí pé gbogbo ẹ̀bi kìí ṣe tàwọn, díẹ̀ wà lọ́wọ́ àwọn oníìbárà náà

Wizkid ko sọrọ laburu nipa iṣẹlẹ to waye ni Ilorin amọ o fi ọrọ sita loju opo rẹ lati fi ifẹ han sawọn eeyan to jade wa wo o.

Igba akọkọ re e ti Wizkid yoo wa kọrin nilu Ilorin.

Ṣe yoo fẹ wa nigba miran? ni ibeere ti ọpọ n beere.

Àkọlé fídíò,

Ǹjẹ́ o mọ pàtàkì igi tó wà ní àyíká rẹ bí?