Premiership: Arsenal ta ọ̀mì 1-1 pẹ̀lú Bournemouth ní ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ àkọ́kọ́ Arteta

Arteta n ki awọn agbabọọlu rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Arsenal ta ọ̀mì 1-1 pẹ̀lú Bournemouth ní ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ àkọ́kọ́ Arteta

Ọmi goolu kọọkan ni Bournemouth ati Arsenal gba ni idije premiership to waye lale Ọjọbọ yii.

Ifẹsẹwọnsẹ akọkọ wọn labẹ olukọni tuntun, Mikel Arteta kii ṣe eyi to mu iyatọ pupọ wa si ti atẹyinwa.

Bournemouth lo kọkọ gba goolu wọle nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju karundinlogoji pẹlu Dan Gosling.

Balogun ikọ Arsenal, Pierre-Emerick Aubameyang lo ra ọmi fun Arsenal nigba to gba goolu wọle ni iṣẹju kẹtalelọgọta ifẹsẹwọnsẹ naa.

Àkọlé fídíò,

Christmas & Border Closure: ìrẹsì dí góòlù fún Kérésì 2019

Pẹlu abajade ifẹsẹwọnsẹ yii, o fihan pe ifẹsẹwọnsẹ kan ṣoṣo ni Arsenal tii bori ninu mẹrindinlogun ti wọn gba sẹyin.

Àkọlé fídíò,

Mo n wa'yawo - Falz