Èkìtì Chieftancy: Àgbéga dé bá Ọba aláde mẹ́rìndínlógún ní Èkìtì

Kayode Fayemi

Oríṣun àwòrán, @ekitistategov

Ijọba ipinlẹ Ekiti ti kede agbega awọn ọba alade mẹrindinlogun ni ipinlẹ naa.

Koda, wọn tun gbe awọn agbegbe sabẹ iṣakoso ara wọn eyi ti oloyinbo n pe ni 'autonomous status'.

Igbesẹ yii ko ṣẹyin aba ti igbimọ to n ṣe agbeyẹwo ipo awọn ọba eyi ti Adajọ J.K.B Aladejana dari rẹ gbe jade.

Kọmiṣọnna fun eto ibaraẹnisọrọ ni ipinlẹ Ekiti, Muyiwa Olumilua lo fidi ọrọ yii mulẹ fun BBC Yoruba.

Olumide ṣalaye pe lẹyin ipade igbimọ alaṣẹ to waye lọsẹ to kọja ni wọn buwọlu ki wọn ṣe agbega awọn ọba.

Ninu awọn ti wọn ṣe agbega wọn si ipele to ga ju ninu ipo lọbalọba gẹgẹ bi Olumilua ti ṣe sọ lati ri:

 • Elewu ti Ewu Ekiti
 • Eleda ti Eda Oniyo Ekiti
 • Onisin ti Isinbode Ekiti
 • Apalufin ti Aisegba Ekiti
 • Olosan ti Osan Ekiti
 • Onigogo ti Igogo Ekiti
 • Olupoti ti Ipoti Ekiti
Àkọlé fídíò,

Akure Kidnap: E túbọ̀ ní sùúrù, a máa wá ọmọ náà rí- Alukoro ọlọ́pàá

 • Oluloro ti Iloro Ekiti
 • Alasa ti Ilasa Ekiti
 • Onimesi ti Imesi Ekiti
 • Olusin ti Usin Ekiti

Awọn ti wọn ṣagbega si ipo to tẹlẹ ni awọn marun un wọn yi:

 • Elesun ti Esun Ekiti
 • Obanikosun ti Ikosu Ekiti
 • Alafon ti Ilafon Ekiti
 • Onikogosi ti Ikogosi Ekiti
 • Olupole ti Ipole Ekiti
Àkọlé fídíò,

Police Brutality: Ojú mi rí tó lọ́wọ́ ọlapàá nítorí Múrí màrùn ún- Adebayo Olaide

Bakan naa ni Olumilua sọ pe wọn gbe awọn ileto kan si ipo iṣakosa farawọn ti oloyinbo n pe ni 'autonomous status'.

Awọn ileto naa ni :

 • Ijọwa (Alajowa ti Ijowa Ekiti to wa ni ipele Kẹta
 • Isaya (Asaya ti Isaya Ekiti to wa ni ipele Kẹta
 • Ahan Ayegunle ( Alahan ti Ahan Ayegunle Ekiti to wa ni ipele Kẹta
 • Owatedo (Oloja Owa ti Owatedo Ekiti to wa ni ipele Kẹta
 • Iro Ayeteju (Owa Ateju ti Iro Ayeteju Ekiti to wa ni ipele Kẹta
Àkọlé fídíò,

Mo n wa'yawo - Falz

O pari ọrọ rẹ pe eto agbega naa ṣi n tẹsiwaju ati pe awọn yoo ṣe ikede miran bi nnkan ba ti ṣe n lọ.

Àkọlé fídíò,

Larisa: Má jẹ́ kí ọjọ́ orí rẹ dí ẹ lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ ohunkóhun to wù ọ