Ìdí tí mo fi gún olólùfẹ́ mi tẹ́lẹ̀ pa - Jacinta Igbke

Jacinta

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán,

Idí ti mo fi gún olólùfẹ́ mi tẹ́lẹ̀ pa- Jacinta Igboke

Olùkọ́binrin nilé ẹkọ alákọbẹrẹ kan nílú Eko tó gún ololufẹ rẹ nigbakan ri lọ́bẹ pa nigba ti igbéyàwó rẹ̀ ku ọjọ díẹ̀ lo ti wà ni gbaga àwọn ọlọpàá bayii.

Lówurọ̀ ọjọ iṣẹ́gun ni Jacinta Igboke gun Arinze Ani pa ni ṣọọbu rẹ̀ lọ́na opopona Ojo ni agbegbe Satellite Town lẹ́yin ti wọ́n ni gbolohun asọ kan.

Iroyin sọ pé Ani to n Kẹmika ni ọjà ọhun ń ṣètò ìgbéyàwó pẹ̀lú obinrin mìíràn ní ọjọ kẹrin oṣù kíní ọdun 2020, lẹ́yìn ti ìná òun àti Ogboke o wọ̀ mọ́ botilẹ̀ jẹ́ pé ìbásepọ náà mu ọmọkunrin ọdun kan abọ dáni.

Àkọlé fídíò,

Akure Kidnap: E túbọ̀ ní sùúrù, a máa wá ọmọ náà rí- Alukoro ọlọ́pàá

Ìwádìí fi han pé ọ̀rọ̀ wọ́n bẹ̀rẹ̀ bi ifẹ́ òtítọ ni ọdun 2016, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ dojuru ni kéte ti Igboke lóyún.

Sùgbọ́n ọ̀rọ̀ bẹ́yìn yọ lọ́jọ́ Iṣẹ́gun nígbà ti Igboke lọ si sọọbu Ani láti lọ gba owo ti yóò fi tóju ọmọ rẹ̀, èyi to si mu gbọnmi-si-omi-otó dáni ti Igboke si fi ọbẹ gun láyà.

Ẹni ọdun mọkàndinlógbọ̀n náà to jẹ́ ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Ebonyi sàlàye fun akọroyin iwé ìròyìn Punch ki àwọn ọlọpàá agbegbe Satellite Town eyi ti Chike Oti saju rẹ̀ to mú u gbogbo ǹkan to fa sábàbi to fi wá ja si ǹkan to ṣẹlẹ̀ yìí.

O ni àwọn òbi Ani ko faramọ ìbáṣepọ̀ àwọn nítori òun dàgbà jù ú lọ, o sì yẹ kó fẹ́ ìyàwó kan ni abule wọ́n ni ìpínlẹ̀ Ebonyi.

O ní " olukọ ilé ẹkọ alákọbẹ̀rẹ̀ ni mi nígbà tí èmi àti Arinze bẹ̀rẹ̀ eré ìfẹ́ wa ni ọdun 2016. Mo lóyun fun un nígbà náà ni àwọn obi rẹ̀ ni mí o le fẹ́ ẹ nitori mo dàgbà jù ú lọ àti pé dàndàn ni ki ó fẹ́ ìyàwó láti abúlé wọ́n.

"Wọ́n bi i ni ọjọ kọkandinlógun, oṣù kọkànlá ọdun 1990 wọ́n si bi èmi ni ọjọ kọkàndinlọ́gbọ̀n oṣù kẹwàá ọdun 1990.

Awọn mọlẹbi rẹ sọ pe ọmọ nìkan ni àwọn yóò gbà"

Igboke ni bótilẹ jẹ́ pé lẹ́yìn ọ̀rọ̀ náà ti orisiri ija ti n ṣẹlẹ̀, àwọn ọlọpàá ni ki Arinze maa san ẹgbẹ̀run mẹ́wàá, pali Indomie kan ati irẹsi fun òun lóṣooṣu, sùgbọ́n Arinze ko ṣe bẹẹ yala óún pinu lati ṣe Igbeyawo, sibẹ̀ yoo maa sọ pé ko si owo.

Igboke ni òun lọ si sọọbu Arinze lojọ ti iṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹ̀ láti bẹ̀ ẹ́ pe ki o fun òun lówó lati ra bàtà ọdún fún ọmọ lẹ́yin ti òun ti lọ ra aṣọ pé ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ni o ti òun ti o si ku díẹ̀ ki òun ko si ẹnu ọkada o ni ìbinu yìí ni òun fi mu ọ̀bẹ láti dààbo bo ara òun ṣùgbọn òun kò mọ ìgbà ti òun gun pa.

O rọ̀ àwọn ọlọpàá láti gbé ọmọ oun lọ si ilé ọmọ alaini iya titi àwọn ẹbi òun yóò fi wá gbé e àti pé òun kò fẹ́ kí ọmọ náà wà lọ́dọ̀ ẹbi Arinze nítori wọn o fi ìya jẹ ẹ́.

Jacinta ni" mo mọ̀ pé mi o lé ri ọmọ mi mọ nítori èmi gan ko ṣe tán láti wà láàye, ṣùgbọ́n àwọn ẹbi Arinze yóò fiya jẹ ọmọ mi nítori wọ́n korira mi.

Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀ Agbénusọ ọlọpàá ìpinlẹ̀ Eko DSP Bala Elkana sọ pé àwọn yóò gbé afurasí náà lo si ẹka to n ṣe iwadii ọdaran fún itẹsiwáju ìwádìí.