APC vs PDP: Àwọn ọmọ Nàìjíríà ò rí ti APC rò mọ́

Aworan aarẹ Buhari ati ami idamọ ẹ gbẹ PDP

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party ti ni lorilẹede Naijiria o, ko sẹni to n ronu ti ẹgbẹ oẹlu APC mọ.

Wakati melo kan sẹyin ni wọn fi sita gẹgẹ bii pipe akiyesi ẹgbẹ oṣelu to wa lori alefa lọwọlọwọ ni Naijiria, All Progressives Congress si ikede wọn pe awọn ti n ro ẹni ti yoo jẹ oludije to n bọ.

Ẹgbẹ oṣelu PDP ni awọn n fi to aarẹ Buhari atawọn adari ẹgbẹ oṣelu APC leti wi pe awọn Naijiria ti tẹsiwaju ninu irinajo wọn kọja ki wọn maa ronu ọrọ APC.

Awọn si ti n pinu ẹni ti yoo gba eku ida iṣejọba ni ọdun 2020 fun ẹgbẹ oṣelu PDP lati mu apapọ ireti wọn ṣẹ gẹgẹ bi ẹgbẹ lati tun orilẹede yii kọ.

Oríṣun àwòrán, OfficialPDPNig

Àkọlé fídíò,

Orí yọ èèyàn mẹ́ta nínú ilé tí ọkọ̀ bàálù dédé já wọ̀

Wọn jẹ ko di mimọ pe dajudaju itan ti fi han pe ati APC ati iṣejọba rẹ, ko ṣee ma ni ni wọn ṣugbọn pe wọn ti de opin irinajo wọn bayii.

Wọn ta abuku ba iṣejọba ẹgbẹ oṣelu APC pe pẹlu iroyin ti oniruuru ẹgbẹ ilẹ okere to fi mọ United States Department of State kọ ṣafihan iwa ipa lasiko idibo, dida ibo ru, didi awọn araalu lọwọ ẹtọ wọn ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Wọn fi ọpọlọpọ nkan to ṣẹlẹ lasiko idibo ipinlẹ Bayelsa ati Kogi ṣe apẹẹrẹ.

Àkọlé fídíò,

Ohun tawọn eeyan Kogi n sọ saaju idibo Gomina

Ẹwẹ, bi PDP ṣe fi igboya kọ ikede wọn yii sita ni awọn ọmọ Naijiria ti ya bo wọn lati fesi.

Bi awọn kan ṣe ni paaga, ki PDP da ọrọ ti wọn sọ pada pe ki wọn ye yin ara wọn tabi tabuku ba ẹgbẹ APC bẹẹ lawọn to fọwọ si ohun ti wọn sọ naa n kan sara si wọn.

Oríṣun àwòrán, OTHER

Àkọlé fídíò,

Kogi vs Bayelsa: Primate Ayodele sọ àsọtẹ́lẹ̀