Plane Crash: Ọkọ̀ báàlù ṣìnà, ó já wọ ilé onílé

Plane Crash: Ọkọ̀ báàlù ṣìnà, ó já wọ ilé onílé

Àfi kí elédúwà máa kó wa yọ lọ́wọ́ bí ọkọ bàálù ṣe máa ń já káàkiri àwọn orílẹ̀èdè.

Baalu ere idaraya ni, o ti sun mọ papakọ ofurufu Danbury Municipal to fẹ balẹ si ni Connecticut, USA.

Ni batiiri ọkọ baalu ba kọ iṣẹ to si doju kọ orule ile kan lẹba ibi to n lọ.

Ile naa ko jina si papakọ ofurufu to fẹ ba si rara. Nigba ti batiiri ọkọ baalu bẹrẹ iṣẹ kiṣẹ lo ba ya si inu ile naa.

Lara awọn to wa ninu ile naa, eeyan kan fara pa. Iroyin si sọ pe awakọ baalu naa ko fara pa pupọ.