Oluwo, ó yẹ kí o bọ̀wọ̀ fún ara rẹ - Olorì àná, Chanel Chin

Olori ati Oluwo

Oríṣun àwòrán, Queen Cha/instagram

Kii ṣe tuntun mọ pe kabiyesi Oluwo ti ilu Iwo, Ọba Rasheed Akanbi ati olori rẹ, Chanel Chin ti kọ ara wọn silẹ. Bi o tilẹ jẹ pe kabiyesi funrarẹ lo kede iyapa laarin wọn, olori Chanel ko fọhun lori ọrọ ana ayafi bayii lori oju opo Instagram rẹ.

Ninu ọrọ to fi sita loju opo naa, Olori ana, Chanel Chin ṣalaye pe lati igba ti Oluwo ti n fọnrere ọrọ naa lori ayelujara, oun mọọmọ dakẹ ni. o fẹsun kan kabiyesi pe oniruuru ọrọ ibanilorukọ jẹ ni kabiyesi ti sọ nipa oun ṣugbọn ọbẹ kii mi nikun agba loun fi ṣe.

O ni ọ̀wọ̀ ti oun ni fun itẹ Oluwo ni ko jẹ ki oun sọrọ si gbogbo oun ti Kabiyesi Oluwo to jẹ ọkọ oun ana n fi sita.

"Amọṣa, bi kabiyesi ko ba bọwọ fun ara rẹ tabi ori itẹ to joko si ...ta ni yoo bọwọ fun un"

Àkọlé fídíò,

Akure Kidnap: E túbọ̀ ní sùúrù, a máa wá ọmọ náà rí- Alukoro ọlọ́pàá

O ni igba akọkọ kọ niyii ti Oluwo yoo maa ba awọn eeyan lorukọ jẹ tabi hun irọ jọ nipa eniyan.

Amọṣa kabiyesi naa ti fesi, oluwo ni bo ba wu olori ana lati duro si Orilẹede naijiria, dede ara rẹ ni o, ṣugbọn gbogbo ẹtọ to yẹ fun irinajo rẹ pada si Canada tii ṣe orilẹede rẹ loun ti ṣe.