Ekifest '19: Ohun t'ọ́kùnrin ń ṣe l'Ekiti, obìnrin lè ṣe é

Nibi ayẹyẹ ajọdun aṣa ọdun yii ni ipinlẹ Ekiti, oniruuru ohun tẹ o tilẹ mọ pe o wa laye yii lẹ o ri nibẹ.

Adari ileeṣẹ Aṣa ni ipinlẹ Ekiti, Wale Ojo sọ fun BBC Yoruba pe awọn n ko awọn aṣa awọn jade lati ṣe afihan rẹ faraye ni.

"A sọ ijó di owó, ohun t'ọ́kùnrin ń ṣe l'Ekiti, obìnrin lè ṣe é". Ọgbni Wale sọ pe Ekiti Festival ti mú ọlá àti oríire wọ ìlú Ekiti, "o n gbe ọgbọn inu ati imọ awọn ọdọ jade sita".

O tẹsiwaju pe gbogbo ìlú tó wà ní Africa ló kù tí Ekiti máa fìwé pè lọ́dún 2020 lati wa wo ọgbọ, imọ ati oye ti Ọlọrun fi sọlẹ si ilu Ekiti.

Lóòtọ́ lóòtọ́, kò sí àṣàdànù nínú àwọ́n afihan ohun agbaṣa ga to waye nibi EKiti Festival 2019.

Ṣé ẹ mọ̀ pé Ekiti ni ìlú tí Ògún Lákááyé wọlẹ̀ sí?

Ilu Orunmila naa, Ekiti ni.

Eṣu tó ma ń dá àbò bo àwọn èèyàn tirẹ̀, Eṣu Ẹlẹ́gbẹ̀rà to maa n gba awọn eeyan lọjọ ibi ba de, ilu Ekiti ni gbogbo wọn ti wa gẹg bi adari aṣa ipinlẹ naa ṣe sọ ọ.

Iyawo gomina ipinlẹ Ekiti, Erelu Bisi Fayemi kadi eto ajdun naa pẹlu rọ̀ iwuri nipa Ekiti pe "Orin Ekiti dá yàtọ̀, ijó wọn, oke nla nla atawọn nkan to jẹ pe owo lawọn eeyan fi lọ n wo wọn nibomiran".