Texas Shooting: Ìsìn dàrú lẹ́yìn t'ágbébọn pàyàn méjì ní ṣọ́ọ̀ṣì

West Freeway Church of Christ
Àkọlé àwòrán Isin n lọ lọwọ ni ile ijọsin West Freeway Church of Christ

Ọrọ di bo o lọ, o yaa mi lẹyin ti ọkunrin kan da'bọn bo'lẹ nile ijọsin West Freeway Church of Christ ni Texas lorilẹede Amẹrika nigba ti isin n lọ lọwọ.

Ọkunrin naa lo ṣadeedee dide to si yinbọn fun eeyan meji, amọ ọwọ palaba rẹ segi nigba olujọsin kan yinbọn fun oun naa, to si gba ibẹ dero ọrun.

Ni kete ti olujọsin naa yinbọn fun agbebọn ọhun tan lawọn olujọsin mii naa fa ibọn yọ, bẹẹ ni wọn doju ibọn kọ ọkunrin agbebọn naa.

Ile iṣẹ ọlọpaa ṣalaye pe awọn meji ti agbẹbọn naa yinbọn fun ti jẹ Ọlọrun ni'pe nile iwosan ti wọn gbe wọn lọ.

Awọn agbofinro ni iwadii ṣi n lọ lọwọ lati mọ ohun ti agbebọn naa ni lọkan gan an to fi dabọn bo lẹ nigba ti ijọsin n lọ lọwọ.

Fọnran iṣẹlẹ ọhun lori ayelujara ṣafihan bi awọn to wa nile ijọsin ṣe n sa si abẹ aga lati rii pe ibọn ko ba wọn nibi ti wọn wa.

Image copyright Getty Images

Alufaa ijọ naa, Jack Cummings sọ fawọn akọroyin pe ọkunrin naa ko ba ṣekupa ọpọ eeyan ti kii ba ṣe pe awọn olujọsin to ni iwe ibọn wa ninu ṣọọṣi naa.

Ẹwẹ, Gomina ipinlẹ Texas, Greg Abbott ti bu ẹnu ẹtẹ lu iṣẹlẹ naa, o ni iwa ipa to buru julọ ni.

Eeyan mejilelogun lawọn agbebọn ṣekupa ninu oṣu kẹjọ ọdun 2019 ni El Paso nipinlẹ Texas bakanna.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn olujọsin

Ninu oṣu kẹjọ kan naa ni agbebọn mii tun yinbọn pa meje ni Odessa-Midland ni Texas.

Lọdun 2017, agbebọn kan tun yinbọn pa olujọsin mẹrindinlọgbọn ninu ijọ Onitẹbọmi kan ni Sutherland Springs lasiko ti isin n lọ lọwọ.

Eleyi lo mu ki ipinlẹ Texas ṣe agbekalẹ ofin to fun awọn eeyan to ba ni iwe ẹri lanfaani lati maa gbe ibọn lọ si ile ijọsin.