Drunk driving: Mu pàrágá wakọ̀ l'Oyo, kóo kó sí gbaga ìjọba

Igo ọti lọwọ awakọ Image copyright Other

Omi tuntun ti ru, ẹja tuntun ti wọ ọ ni ipinlẹ Oyo. Awakọ mẹẹdọgbọn ni ọwọ ofin ti tẹ nipinlẹ naa lori ẹsun pe wọn n muti nigba ti wọn tun n wa ọkọ.

Kọmiṣọna fun eto iroyin nipinlẹ naa, Wasiu Olatubosun to ba BBC Yoruba sọrọ ṣalaye pe igbesẹ yii yoo jẹ ẹkọ fawọn awakọ mii ti wọn ba tun fẹ hu iru iwa bẹẹ.

Lopin ọsẹ to lọ ni ajọ to n ri si idari ọkọ ni ipinlẹ Oyo, OYRTMA mu awọn awakọ naa pẹlu iranlọwọ ẹrọ igbalode to le ṣafihan bi eeyan ba mu ọti.

Kọmiṣọnna Olatubọsun sọ pe gbogbo awọn awakọ mẹẹdọgbọn naa ni yoo foju ba ile ẹjọ.

Kọmiṣọnna ni ile ẹjọ si ni yoo sọ pato ijiya to tọ si wọn.

Ọgbẹni Olatubosun tun fi kun ọrọ rẹ pe mimu awọn awakọ to n mu ọti kii ṣe ninu asiko pọpọsinsin nikan.

Image copyright Facebook/Inside Oyo

Kọmiṣọnna fun eto iroyin nipinlẹ ni eto naa yoo tẹsiwaju ninu ọdun 2020 nitori ẹmi awọn eeyan ipinlẹ jẹ ijọba Gomina Ṣeyi Makinde logun.

Ẹwẹ, alaga OYRTMA, Dokita Akin Fagbemi ṣalaye pe igbesẹ ajọ wọn lati mu awọn ọmuti awakọ wa ni ibamu pẹlu iṣẹ ajọ naa lati dẹkun ijamba ọkọ tawọn ọmuti awakọ n ṣe okunfa rẹ nipinlẹ Oyo.

O fi kun ọrọ rẹ pe ni opopona Ring-Road, Iwo-Road, ati Moniya si Ogbomoso ni wọn ti mu awọn awakọ ọhun.