2019 in Retrospect: Wo àwọn èèyàn jáńkán tí yóò rékọjá sí 2020 nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n

Alfah Babtunde, Seun Egbegbe ati Uzor kalu Image copyright @others

Oriṣiriṣi ohun lo ṣẹlẹ lọdun 2019, ọpọ lo ṣe igbeyawo, awọn kan kọle, awọn mii ra ilẹ, awọn kan dero oke okun, bẹẹ lawọn miran dero ẹwọn.

Ninu awọn ti yoo ṣe ọdun tuntun ninu ẹwọn lati ri awọn eeyan jankan bii oloṣelu, pasitọ, oṣere tiata, ati bẹbẹ lọ.

Ẹ jẹ ka wo diẹ lara awọn eeyan ọhun.

1. Alfa Babatunde Sotitobire

Ọpọ ni ko mọ ijọ kan torukọ rẹ n jẹ Sotitibire Miracle Centre nilu Akure tẹlẹ, ṣugbọn okiki ile ijọsin ọhun kan lẹyin ti ọmọ ọdun kan o le diẹ dede poora nile ijọsin naa.

Bi rere bi awada, ọrọ naa di ti agọ ọlọpaa, eyi mu ki Alfa Babatunde Sotitobire dero agọ ajọ ọtẹmuyẹ DSS.

Ṣugbọn lọjọ kẹtalelogun, oṣu Kejila ọdun yii ni ile ẹjọ to wa ni Oke Eda nilu Akure paṣẹ pe ki wọn fi pasitọ ọhun si ọgba ẹwọn Olokuta nilu Akure, ki igbẹjọ rẹ to tẹsiwaju.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionṢé lóòtọ́, báwọn wọ̀nyìí ṣe sọ ọ́ ló rí fún gbogbo yín lọ́dún 2019?

2. Orji Uzor Kalu

Gomina ipinlẹ Abia tẹlẹ, Orji Uzor Kalu jẹ ọkan lara awọn oloṣelu ti orukọ rẹ tan lọdun 2019 lori ẹsun ṣisọwo ilu baṣubaṣu.

Ṣaaju ni ajọ to n gbogun ti iwa jẹgudujẹra, EFCC ti fẹsun kan pe o ko owo ilu sapo nigba iṣejọba rẹ gẹgẹ bi gomina laarin ọdun 199 si 2007.

Lẹyinorẹyin, ile ẹjọ giga kan nilu Eko ran lẹwọn ọdun mejila lọjọ karun un oṣu Kejila ọdun 2019.

To n tumọ si pe, inu ọgba ẹwọn ni gomina ana ọhun yoo ṣe ọdun tuntun.

3. Seun Egbegbe

Gbajumọ laarin awọn oṣere tiata Yoruba ni Olajide Kareeem, ti ọpọ eeyan mọ si Seun Egbegbe jẹ, koda o gbajumọ to bẹ ti awọn olorin kan ma n kan sara ninu awo wọn.

Wọn ni o lu awọn to ma n ṣẹ owo ilẹ okeere to le ni ogoji ni jibiti, lẹyin to parọ fun wọn pe oun ni owo lati ṣe laarin ọdun 2015 si 2017.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Àṣà wa l'Ekiti ló dára jú lórílẹ̀èdè Nàìjíríà'

Oṣu Keji ọdun 2017 ni adajọ Oluremi Oguntoyinbo ni ki wọn gba oniduro Egbegbe pẹlu miliọnu marun un naira, ṣugbọn o ni ko wa lọgba lọgba ẹwọn titi ti yoo fi ri owo itanran ọhun.

Lati igba naa ni Egbegb ti dero ẹwon latari pe ko sẹni to le san owo ọhun.

4. Ibrahim El-Zakzaky

Olori ẹlẹsin Musulumi Shia ni Ibrahim El-Zakzaky, oun si ni adari awọn Islamic Movement of Nigeria to da silẹ lọdun 1970.

Ọdun 2018 ni ijọba ipinlẹ Kaduna fẹsun ipaniyan kan oun ati iyawo rẹ, Zeenah Ibrahim ti wọn si gbe wọn lọ ile ẹjọ lẹyin ti awọn ọmọ lẹyin rẹ dena olori ologun Naijiria ni Kaduna.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAkure Kidnap: E túbọ̀ ní sùúrù, a máa wá ọmọ náà rí- Alukoro ọlọ́pàá

Lati ọdun naa ni El-Zakzaky ti bẹrẹ si ni foju wina ijọba Naijiria.

Bo tilẹ jẹ pe wọn ṣejọ rẹ, ile ẹjọ si ti ni ki wọn tu silẹ, o ṣeni laanu pe inu ẹwọn ni ọdun tuntun yoo ba okunrin ọhun.

5. Mohammed Adoke

Ọjọ kejidinlọgbọn oṣu Kejila ọdun 2015 ni ajọ EFCC fi iwe pe Mohammed Bello Adoke lori ẹsun magomago epo Malabu ti owo rẹ le ni biliọnu mẹfa naira.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionChristmas: Jesu ni ọjọ́ ọ̀la àti ibi ìyanu mi- Jaga

Ṣugbọn ọjọ kẹtadinlogun oṣu Kẹrin ọdunn 2019 ni ile ẹjọ giga kan nilu Abuja ni ki wọn fi pampẹ ofin gbe ati awọn mii lori ọrọ owo naa.

Ni kete to pada wa lati ilu Dubai ni awọn agbofinro nọwọ gan.

Lẹyinorẹyin, inu ahamọ ni Adoke wa bayii ti awọn agborinro si sọ pe o n fọwọsowọpọ pẹlu wọn ninu iwaadi ti wọn ṣe.