Saraki vs Abdulrazaq: Àwọn arúgbó ní kí ìjọba máà ṣe wó ilé arúgbó m'áwọn lórí

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀwọn arúgbó ní kí ìjọba máà ṣe wó ilé arúgbó m'áwọn lórí

Ọrọ lori ile arugbo ti Ijọba ipinlẹ Kwara lawọn fẹ gba ilẹ naa pada lọwọ aarẹ ile aṣofin agba tẹlẹ Bukola Saraki ti gba ọna mi yọ.

Eyi ko ṣẹyin bi awọn iya arugbo kan nilu Ilorin ti ṣe ṣe iwọde ladugbo Iloffa Road ti ile Baba Saraki ''Oloye'' kalẹ si.

Ninu ifọrọwerọ pẹlu awọn akọroyin awọn Iya arugbọ naa parọwa si Gomina ipinlẹ Kwara lati ma ṣe wo ile to wa lori ilẹ naa nitori pe ibẹ lawọn ti n ri jijẹ mimu.

Ọkan ninu wọn to sọrọ pẹlu awọn akọroyin sọ pe ''Eeyan ki ṣe nkan ti eeyan ko to lati ṣe .A n bẹ Gomina ko ma wo ile arugbo''

Bi a ko ba gbagbe, fakinfa kan n waye lẹnu ọjọ mẹta yi laarin Ijọba Kwara ati aarẹ ile aṣofin agba tẹlẹ Bukola Saraki lori ilẹ ti Baba Saraki,Olusola Saraki kọ ile to pe ni ile arugbo le lori.

Ninu ikede ti Ijọba fi sita soju opoTwitter, wọn sọ pe awọn gbẹsẹ le ilẹ naa nitori pe ko ni iwe aṣẹ to yẹ.

Wọn tẹsiwaju pe ọna eru ni Saraki fi gba ilẹ naa fun Baba rẹ lasiko to wa lori alefa nitori ọtọ ni nkan ti ijọba fẹ fi ilẹ naa ṣe.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Mí ò ya wèrè, mí ò burú, ọ̀nà àtijẹ là ń wá'

Dokita Bukola Saraki naa ko jẹ ki ọrọ yi balẹ ki o to fi esi sita pe oun ko ṣarifin si baba ẹnikẹni nigba ti ohun wa lori oye nitori naa oun ko ni gba ki ijọba Gomina Abdulrahaman Abdulrazaq ṣarifin si baba oun.

Saraki tẹsiwaju pe gbogbo nkan to ba gba lohun yoo fi ba ijọba Kwara fa lori ilẹ to sọ pe Baba oun gba iwe aṣẹ ki o to kọ ile si ori rẹ.

Ni ilu Ilorin ati kaakiri ipinlẹ Kwara, ọrọ yi ti n mu iriwisi ọtọọtọ wa ti awọn kan si ni ki wọn fi ẹlẹ yanju ọrọ naa ki o ba ma da wahala silẹ nilu.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAkure Kidnap: E túbọ̀ ní sùúrù, a máa wá ọmọ náà rí- Alukoro ọlọ́pàá