Prophecy 2020: Primate Ayodele, Baba Adeboye àti Father Mbaka sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa 2020!

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionProphecy 2020: Adeboye àti Ayọdele sọ nípa ọjọ́ ìwájú 2020

Primate Ayodel kilọ lori ohun to le ṣẹlẹ ninu idibo ipinlẹ Edo ati Ondo.

Bakan naa lo sọrọ lori awọn Boko Haram ati pe 2021 ni ọwọ maa tẹ Shekau olori wọn.

Primate Ayodele ti ijọ INRI evangelical sọrọ yii lasiko eto ti ijọ naa fi n pese iranlọwọ ohun ini fawọn opo ati alaini ni awujọ nile ijọsin wọn ni Eko.

Iyipada ijọba, ilẹ riri yoo waye ni ọpọlọpọ orilẹ-ede lagbaye- Pasitọ Adeboye

Bakan naa ni Baba Adeboye ti ijọ Redeemed Christian Church of God naa pe fun adura ki ọrọ iṣipo pada to maa waye ni 2020 ati ilẹ riri ma ga ju ara lọ.

Oludari Agba fun ijọ irapada, Redeemed Christian Church of God (RCCG), Pasito Enoch Adeboye ti ni ọpọlọpọ iṣẹlẹ ni yoo waye kaakiri agbaye ni ọdun 2020.

Pasitọ Adeboye ni iyipada yoo deba isejoba lagbaye, eleyii ti yoo mu irọun dani ni awọn agbegbe kan, nigba ti ti awọn miran yoo mu rogbodiyan lọwọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionṢé lóòtọ́, báwọn wọ̀nyìí ṣe sọ ọ́ ló rí fún gbogbo yín lọ́dún 2019?

Ògo tuntun yóò sọ ní ọdún 2020!- Olukoya ti ìjọ MFM

Oludasilẹ ijọ Mountain of Fire and Miracles Ministries, MFM, Daniel Odukoya ti fi ọpọlọpọ aṣọtẹlẹ silẹ fun ọdun 2020.

Image copyright Others
Àkọlé àwòrán Ohun tí ó wọ́pọ̀ ni orilẹ̀-èdè Naijiria ni kí àwọn olórí Ilé Ijọsìn kọ̀ọ̀kan sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọdún tuntun ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún.

Olukoya to pe ọdun 2020 ni "ọdun isọji ati ogo tuntun", rọ awọn ọmọ Naijiria lati gbadura ki ohun gbogbo ma dojuru ni 2020.

Ninu ọrọ rẹ, awọn adari ni iye wọn yoo di ẹni ana.

O fikun un wi pe ẹni to ba tapa si ofin Olorun yoo ru igi oyin ti adura itusilẹ ko ni le e gba a silẹ.

Ohun tí ó wọ́pọ̀ ni orilẹ̀-èdè Naijiria ni kí àwọn olórí Ilé Ijọsìn kọ̀ọ̀kan sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọdún tuntun ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún.

Ẹ gbàdúrà kí ogun má bẹ́ sílẹ̀ ní 2020- Primate Ayodele

Oludasilẹ Ijọ INRI Evangelical Spiritual Church, Oke-Afa, ni Ejigbo ni ipinlẹ Eko, Primate Babatunde Elijah Ayodele ti sọ asọtẹlẹ nipa ọdun 2020.

Image copyright Others
Àkọlé àwòrán Primate Ayodele, Baba Adeboye àti Father Mbaka sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọdún 2020!

Ayodele sọ eyi lasiko ọdun tuntun nigba to n sọrọ nipa Aarẹ Muhammadu Buhari; Igbakeji aarẹ, Yemi Osinbajo ati adari ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Tinubu pẹlu ẹka ijọba miran.

O ni ija, asọ ati ipaniyan yoo pọsi lorilẹede Naijiria, bẹẹ ni rogbodiyan yoo peleke si kaakiri agbaye.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption2020: Oloye Awurela Ifaleke ti wúré ọdún ìgbéga fún kóówá

Oludasilẹ ijo INRI tun fikun un wi pe ọrọ aje yoo tubọ dẹnukọlẹ si nii.

O ni ki Tinubu ṣọra ki o rii pe oun n ṣe ohun to tọ fun awọn eniyan Naijiria, ko fi t'Olorun ṣe ninu ilepa rẹ.

APC yoo dide lodi si ijọba laipẹ nitori pe Osinbajọ àti Buhari yoo ri wahala

Primate Ayodele wa kesi awọn ọmọ Niajiria lati gbohun adura soke fun orilẹ-ede naa, ki ijamba, ikọlu ati ibugbamu oloro ma ba a peleke si lorilẹ-ede Naijiria.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌbẹ Ẹgusi sise ati jijẹ

Bakan naa ni Baba Adeboye ni adura nikan lo le e ṣẹgun ilẹ riri ati awọn ijamba miran ti yoo waye ni ọdun 2020.

Baba Adeboye ni ilẹ yoo lanu, bi iru eleyii ti ko i tii ṣẹlẹ ri lọdun 2020.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Òṣìṣẹ́ Bánkì ni mí l'Amẹ́ríkà kí n tó bẹ̀rẹ̀ Tíátà'

Kini asọtẹlẹ Fada Mbaka nile Igbo ni Guusu Naijiria?

Bakan naa ni Fada Ejike Mbaka to ti ijọ Adoration Ministry ti ni iyipada yoo deba ijọba Naijiria ni ipinlẹ ati ni ijọba apapọ.

O ni ayipada nla maa deba iṣelu ipinlẹ Imo ni guusu Naijiria ni 2020.

O tun pin agbara ti ẹmi fun awọn kan ninu ẹgbẹ oṣelu kan to ni pe ki wọn gba agbara lati bẹrẹ iṣẹ

Kini Aarẹ Buhari wa ri sọ leni lori ọrọ Naijiria?

Aare Buhari tilẹ sọ wi pe igba ọtun lo de ni Naijiria, ati wi pe gbogbo ileri ti awọn ti ṣe ni awọn yoo mu ṣẹ.

O tun menuba awọn iṣẹ akanṣe ti ijọba rẹ fẹ ṣe ni 2020 pe Ó ti tán fún mí lọ́dún 2023- Ààrẹ Muhammadu Buhari

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption#Queen Dihya: Obinrin tó gbógun tàwọn agbésùnmọ̀mí ni Algeria