Contraband: Ọlọ́pàá Uganda rí ohun ìpara olóró nínú ‘baby’

Uganda

Oríṣun àwòrán, Dicksons Kateshumbwa

Àkọlé àwòrán,

Àwọn aláṣẹ ilẹ̀ Uganda ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn ènìyàn ti ń gbé òògùn olóró àti àwọn ohun tí ìjọba ti wọ́gilé wọ ilẹ̀ náà.

Ile iṣẹ to n gbogun ti iwa gbigbe oogun oloro lọna aitọ wọle ti fi panpẹ ọba mu arakunrin to n gbe ohun ipara oloro si inu ‘baby’ onike.

Ọga Agba aṣọbode lorilẹ-ede Uganda, Dicksons Kateshumbwa lo ni arakunrin naa to gbe 'baby' pọn sẹyin ni ọwọ tẹ ni ibode Democratic Republic of Congo.

Dicksons Kateshumbwa ni oju opo twitter rẹ sọ wi pe awọn to n ṣisẹ fayawọ kii ye pa eniyan lẹrin.

Àkọlé fídíò,

Ifa Priest: ọdún mọ́kànlá ni mo fi ṣe iṣẹ́ agbejọ́rọ̀ kí n tó gbọ́ràn si Ifá lẹ́nu

Dicksons ni arakunrin ti ọwọ ba naa kọ ọpọlọpọ ohun ipara ati ọṣẹ iwe sinu ‘baby’ naa to si gbe e pọn bi ọmọ, ni ọna lati maṣe jẹ ki wọn fura si oun ti wọn gbe naa.

Àkọlé fídíò,

Ọbẹ̀ ni, ẹran ni o, irú oúnjẹ wo lẹ́ fẹ́, ká báa yín sè é wá sílé yín?

Ọga Agba aṣọbode lorilẹede Uganda ni awọn eniyan ma n gbe oṣẹ ati ohun ipara to n mu eniyan pọn fo wọlẹ lati ẹnu ibode DR Congo, eleyii ti awọn ti wọgile ni ọpọ igba.

Bakan naa lo fi lede pe ọdun 2016 ni awọn ti wọgile gbigbe ọṣẹ ipara borabora wọlẹ si orilẹ-ede naa, nitori o ni awọn ohun ipalara bi hydroquinone ati mercury to n ṣe ipalara fun ara.

Àkọlé fídíò,

Eduardo: Mo ń jí mọ́tò pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi nítorí pé mo fẹ́ di 'Big boy'