Supreme Court: Ilé ẹjọ́ gíga jùlọ sún ìgbẹ́jọ́ ìbò Kano, Imo àti Sokoto

Ile ẹjọ giga ju lọ

Oríṣun àwòrán, OTHER

Ile ẹjọ to ga ju lọ lorilẹede Naijiria ti sun igbẹjọ to yẹ ko waye lonii lori ibo ipinlẹ mẹfa lorilẹede yii siwaju.

Adajọ agba Naijiria, Adajọ Tanko Muhammad lo pa aṣẹ naa lẹyin ti awọn oniṣẹ aabo ko lee kapa aduru ero to wa nibẹ ati ariwo pupọ ninu ile ẹjọ.

Adajọ Muhammad lo dari igbimọ igbẹjọ ẹlẹni meje to jẹ asan adajọ lati gbọ ẹsun awuyewuye to jẹyọ nibi ibo gomina ipinlẹ Bauchi, Kano, Sokoto, Plateau, Benue ati ipinlẹ Imo.

Àkọlé fídíò,

Ifa Priest: ọdún mọ́kànlá ni mo fi ṣe iṣẹ́ agbejọ́rọ̀ kí n tó gbọ́ràn si Ifá lẹ́nu

Ẹwẹ, lẹyin iṣẹju diẹ ti igbẹjọ bẹrẹ ni ijoko ile ẹjọ dide nigba ti wọn n gbọ ariwo ero to wa ninu ile ẹjọ ti wọn ko si le kapa rẹ ti adajọ si sun un siwaju di ọjọ kẹrinla, oṣu kinni, ọdun 2020.

Lati wa jẹ ki ero dinku, adajọ agba pasẹ pe ki awọn tọ́rọ̀ kan ma mu wa ju agbẹjọrọ marun un lọ.

Ni kete to si ti fun wọn laye lati ṣe ẹlẹri pe ijoko na bẹrẹ ni adajọ Muhammad paṣẹ pe ki wọn so igbẹjọ naa rọ na.

Lẹyin eyi wọn ni ki awọn oloṣelu ti ọrọ kankan o kan ṣugbọn to wa sile ẹjọ jade kuro ninu ile ẹjọ ti awọn ọlọpaa si lo aja lati ran wọ́n lọwọ ki ero le din ku.

Ṣaaju, oni ọjọ Aje lo yẹ ki ile-ẹjọ to ga ju lọ ni Naijiria dajọ awuyewuye to jẹyọ nibi ibo gomina awọn ipinlẹ naa.

Oludije fun ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP, Abba Kabir Yusuf lo pe oludije ẹgbẹ oṣelu APC, Abdullahi Umar Ganduje to jawe olubori ninu ibo gomina ipinlẹ Kano lẹjọ.

Àkọlé fídíò,

Jide Kosọkọ: Isẹ́ tíátà yóò gòkè tíjọba bá gbówó kalẹ̀ láti seré

Ile ẹjọ kotẹmilọrun ti kọkọ dajọ pe ko si ẹri to daju to fidi rẹ mulẹ pe magomago wa ninu eto idibo to gbe Ganduje wọle.

Rogbodiyan nla bẹ silẹ lasiko idibo ati lẹyin idibo ọhun nipinlẹ Kano lẹyin tawọn ọdọ ti wọn jẹ alatilẹyin oludije ẹgbẹ oṣelu PDP yari pe Kabir Yusuf lo yẹ ko wọle ibo naa.

Ibo gomina Ipinlẹ Sokoto

Oludije ibo gomina fẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Sokoto, Ahmad Aminu Waziri lo pe gomina Aminu Waziri Tambuwal to jawe olubori ninu ibo gomina ipinlẹ naa.

Amọ, ile ẹjọ kotẹmilọrun nipinlẹ naa ati ipinlẹ Kaduna da ẹjọ naa nun, eyi lo jẹ ki Aliyu mori le ile ẹjọ to ga julọ l'Abuja.

Koda, atundi ibo tiẹ wa nipinlẹ Sokoto ati Kano, amọ ibi pẹlẹbẹ naa ni ọbẹ fi lelẹ.

Àkọlé fídíò,

Eduardo: Mo ń jí mọ́tò pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi nítorí pé mo fẹ́ di 'Big boy'

Ibo gomina Ipinlẹ Imo

Oludije ibo gomina fẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Imo, Hope Uzodimma naa yoo mọ lonii bo ya oun lo wọle ibo gomina ipinlẹ Imo.

Ile-ẹjọ kotẹmilọrun ti kọkọ da ẹjọ rẹ lẹyin to tako bi ajọ eleto idibo INEC ti kede gomina Emeka Ihedioha gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ninu eto idibo naa.

Àkọlé fídíò,

Ọbẹ̀ ni, ẹran ni o, irú oúnjẹ wo lẹ́ fẹ́, ká báa yín sè é wá sílé yín?

Ẹwẹ, gbajugbaja ọjiṣẹ Ọlọrun nipinlẹ Enugu, Fada Ejike Mbaka sọ asọtẹlẹ nipari ọdun 2019 pe ki Gomina Ihedioha palẹ ẹru rẹ mọ nitori Uzodimma ẹgbẹ APC yoo di gomina ipinlẹ Imo lọdun yii.