Omolola Ajayi ti bọ́ l'óko ẹrú lẹ́yìn tí ìjọba Nàìjíríà dá sí ọ̀rọ̀ rẹ̀

Omolola ajayi ati awọn aṣoju Naijiria
Àkọlé àwòrán,

Omolola Ajayi lo wọ aṣọ otutu funfun laari awọn to duro ninu aworan yii.

Orilẹ-ede Naijiria ti doola ọmọbinrin kan, Omolola Ajayi, ti awọn kan ta si oko ẹru l'orilẹ-ede Lebanon.

Oludari ajọ to n ri si ọrọ awọn ọmọ Naijria nilẹ okeere, Abike Dabiri-Erewa lo fi ikede naa sita l'ori opo ayelujara Twitter rẹ nirọlẹ ọjọ aje.

Ninu ikede naa, Arabinrin Dabiri-Erewa sọ pe ọmọbinrin yii ti wa ni ọdọ aṣoju Naijiria ni Beirut bayii, ti "inu rẹ si dun lati wa ni ibi aabo".

Fidio alaye ti arabinrin Ọmọlọla se ree, eyi to gba ori ayelujara kan. Ninu fidio naa, Omolola ṣalaye pe ẹnikan ti oun mọ lo tan oun lọ si orilẹ-ede Lebanon pe oun yoo ma ṣiṣẹ olukọ ede Gẹẹsi. Ṣugbọn, oko ẹru lo ta oun si.

Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrazak koro oju si iwa fifi eeyan e owo ẹru to n gogo sii lorilẹede yii.

Atẹjade kan ti amugbalẹgbẹ rẹ feto iroyin, Rafiu Ajakaye fi sita lorukọ gomina naa ṣe apejuwe iwa yii gẹgẹ bi ika si ọmọniyan eyi ti ko lee jẹ itẹwọgba rara.

Bakan naa lo tun ṣekilọ pe ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ pe o n san iru asọ yii ṣe oro ko ni lọ laijiya, ti onitọhun yoo si tun fi'mu kata ofin.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Atẹjade naa fi kun un pe inu gomina Abdulrahman ko dun rara si fọnran aworan to gbode nipa arabinrin Ọmọlọla Ajayi.

Oun ni wọn fi sọko lọ ṣe owo ẹru nilu Lebanon, ẹni ti awọn obi rẹ n gbe nilu Ilọrin, tii se olu ilu nipinlẹ Kwara.

"Gomina ti wa bu ẹnu atẹ lu iru iwa ika bayii, to si ti pasẹ fun awọn agbofinro lati tu isu de isalẹ ikoko lori isẹlẹ naa, ti ọwọ si ti tẹ awọn afurasi mẹta, ti wọn ni o n sọ nipa isẹlẹ naa."

Àkọlé fídíò,

Ifa Priest: ọdún mọ́kànlá ni mo fi ṣe iṣẹ́ agbejọ́rọ̀ kí n tó gbọ́ràn si Ifá lẹ́nu

Atẹjade naa fikun pe ọwọ ba Wasit Muhammed, tii se ọmọ orilẹ-ede Lebanon, Olatunji Sanusi, tii se agbẹjọro ati ẹnikan ti wọn pe orukọ rẹ ni Tunde.

Sugbọn wọn ni ọkunrin kan to n jẹ Joseph, toun naa mọ nipa bi wọn se fi Ọmọlọla se owo ẹru, lo ti na papa bora.

Àkọlé fídíò,

Ọbẹ̀ ni, ẹran ni o, irú oúnjẹ wo lẹ́ fẹ́, ká báa yín sè é wá sílé yín?

Iroyin ọhun fikun pe Gomina Abdulrahman ti wa n kan si awọn ileesẹ ijọba apapọ ti ọrọ fifi eeyan se owo ẹru kan, to fi mọ ileesẹ to wa fọrọ ilẹ okeere ati ajọ agbaye to n ri si iwa sise atipo loke okun, lati tete mọ bi wọn yoo se gba Ọmọlọla silẹ lọwọ awọn eeyan to mu sigbekun.

Àkọlé fídíò,

Eduardo: Mo ń jí mọ́tò pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi nítorí pé mo fẹ́ di 'Big boy'