Biafra at 50: Ọ̀nà tí ẹja panla gbà di gbajúgbajà nínú ìṣasùn nìyí

panla Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Ẹja Panla to wọ Naijiria bii ounjẹ iranlọwọ nigba ogun Biafra lo ti di ounjẹ tolowo n gbadun bayii.

Ṣe o mọ ẹja Panla? Ṣaṣa lẹni to lee ni oun ko mọ ẹja Panla lorilẹ-ede Naijiria.

Lootọ awọn mẹkunnu ni a mọ ẹja yii mọ ni igba kan ṣugbọn bayii, awọn ọtọkulu paapaa ti n karamasiki ẹja yii bayii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBakare Mubarak: ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń fẹ́ dúró sí ẹgbẹ́ mí tójú si máa n tì mí

Itan sọ wi pe, asiko ogun abẹle to waye laarin ọdun 1967 si 1970 fa ọpọlọpọ iyàn, iyẹn airi ounjẹ jẹ fawọn ọmọde ati agbalagba.

Ogun yii waye nigba ti awọn iran Igbo ni wọn fẹ ya kuro lara orilẹ-ede Naijiria ki awọn lọ da duro.

Bẹẹ, awọn alaṣẹ orilẹ-ede Naijiria lasiko naa yari pe awọn ko ni fi iran Igbo silẹ lati lọ da duro.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọ̀nà tí ẹja panla gbà di gbajúgbajà nínú ìṣasùn nìyí

Iroyin sọ pe, ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta o din ogun, 480,000 lawọn ọmọde to fara kaaṣa iyan to mu lasiko naa.

Ida mọkanlelọgbọn ninu ọgọrun un, 31% lọjọ ori wọn ko ju ọdun ọdun marun un lọ.

Ọpọlọpọ obi lo si n foju ara wọn ri iku ọmọ wọn pẹlu ibanujẹ.

Ounjẹ jijẹ jẹ ara ohun to maa n fara gba nigba ogun jija.

Amọṣa, ogun abẹle to waye yii ati awọn wahala ọwọngogo ounjẹ to waye nipasẹ rẹ lo mu ki ọpọ awọn ajọ aṣeranwọ lagbaye o dide iranlọwọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIfa Priest: ọdún mọ́kànlá ni mo fi ṣe iṣẹ́ agbejọ́rọ̀ kí n tó gbọ́ràn si Ifá lẹ́nu

Gẹgẹ bi itan ṣe sọ, lara awọn iranwọ ti ajọ aṣeranwọ lati orilẹ-ede Norway gbe kalẹ fun awọn ọmọde lagbegbe ile Igbo to n jagun Biafra ti aisan Kwaṣọkọ n ba finra nipasẹ airounjẹ jẹ lasiko ogun abẹle naa ni ẹja Panla.

Ẹja jẹ ara ohun amuṣọrọ fawọn eeyan orilẹ-ede Norway.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌbẹ̀ ni, ẹran ni o, irú oúnjẹ wo lẹ́ fẹ́, ká báa yín sè é wá sílé yín?

Ọpọ iran Igbo lo dupẹ lọwọ orilẹ-ede Norway fun bi wọn ṣe ko ẹja panla ranṣẹ lasiko ogun yii ki awọn ọmọ Biafra ma lọ ku tan nitori airi ounjẹ aṣaraloore jẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionJide Kosọkọ: Isẹ́ tíátà yóò gòkè tíjọba bá gbówó kalẹ̀ láti seré

Bi o tilẹ jẹ wi pe ẹja Panla ti di wọọ kilu mọ ninu ikoko ọbẹ awọn ọmọ Naijiria, itan to gbee di odu ni iṣasun niyi.

Image copyright Getty Images