Finance Bill: VAT di 7.5% láti 5% lẹ́yìn tí ààrẹ Buhari buwọ́lu àbá ètò ìnáwó

Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Twitter/Bashir Ahmad

Àkọlé àwòrán,

VAT di 7.5% láti 5% lẹ́yìn tí ààrẹ Buhari buwọ́lu àbá ètò ìnáwó

Lẹyin ọ rẹyin, owo ori VAT ti di 7.5% lati 5% lẹyin ti aarẹ Muhammadu Buhari buwọlu aba eto inawo ọdun 2019 lonii ọjọ Aje.

Aba ọhun ati aba iṣuna ọdun 2020 ni ile aṣofin gbe lọ siwaju aarẹ papọ ki ọdun 2019 to pari.

Amọ, Buhari buwọlu aba eto inawo lẹyin ọjọ mẹtadinlọgbọn to ti kọkọ buwọlu eto iṣuna ọdun 2020.

Buhari sọ loju opo Twitter rẹ pe o jẹ idunnu fun oun lati buwọlu aba eto inawo nitori aba naa yoo ṣatunṣe ọrọ owo ori.

Aarẹ ni aba yii to ti di ofin ni yoo jẹ ki ilana owo ori sisan ni Naijiria wa ni ibamu pẹlu gbogbo agbaye.

Aarẹ Buhari ni eyi nigba akọkọ ti aba eto inawo yoo tẹle aba eto iṣuna lati rii pe gbogbo eto lọ bo to yẹ lati igba ti orilẹede Naijiria ti pada si ijọba awarawa lọdun 1999.

Ofin yii yoo tun mu ayipada ba owo ori epo rọbi, ibode, owo ori ọja tariifu, owo ori ile iṣẹ ati owo ori awọn araalu lapaapọ.

Pẹlu ofin ti aarẹ Buhari buwọlu yii, awọn ile iṣẹ ti ere wọn ko ba to miliọnu mẹẹdọgbọn ko ni maa san owo ori lori ere ti wọn ba jẹ mọ.

Àkọlé fídíò,

Ifa Priest: ọdún mọ́kànlá ni mo fi ṣe iṣẹ́ agbejọ́rọ̀ kí n tó gbọ́ràn si Ifá lẹ́nu

Bakan naa, owo ori tawọn ile iṣẹ ifowopamọ maa n yọ tẹlẹ lori ẹgbẹrun un kan naira yoo bẹrẹ lati ẹgbẹrun un mẹwaa naira bayii.

Àkọlé fídíò,

Eduardo: Mo ń jí mọ́tò pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi nítorí pé mo fẹ́ di 'Big boy'