Wasiu Ayinde: Ó pọn dandan fún Mayegun láti ri pé àláfíà jọba

Alhaji Wasiu Ayinde jẹ Mayegun

Oríṣun àwòrán, Instagram/K1 the ultimate

Àkọlé àwòrán,

Ó pọn dandan fún Mayegun láti ri pé àlaáfíà jọba

Ile Ọba Alaafin ti ilu Oyo ti sọ ipa ti Mayegun ti ilẹ Yoruba, Wasiu Ayinde yoo ma a ko ni ilẹ Yoruba.

Ọmọọba Alaafin, Bunmi Labiyi lọ sọ bẹẹ fun BBC Yoruba lasiko ti a n fi ọrọ wa a lẹnu wọ nipa iṣẹ ti ipo naa wa fun ni ilẹ Yoruba.

Labiyi ni ipa gboogi ti Maiyegunyoo ko ni lati ri wi alaafia to niye gbinlẹ ni ilẹ Yoruba.

Ti ija ba waye laarin ileto si ileto, tabi ipinlẹ si ipinlẹ, ẹtọ Maiyegun ni lati ri wi pe wọn wa opin si aawọ naa laarin ilu mejeeji.

Lẹyin naa ni yoo ri daju pe ibasẹpọ to dan mọran wa larin agbeegbe tabi ipinlẹ ti asọ tabi ija naa ti waye.

O fikun pe, Maiyegun naa ma n dunadura laarin awọn ọmọ Yoruba, lọna ati mu idẹru, alaafia, igbeleke asa ati alaafia gbilẹ si ni ilẹ Yoruba.

Oríṣun àwòrán, Instagram/saheedosupa

Sẹ Maiyegun Meji Lo Wa Ni Ilẹ Yoruba?

Alaafin ti Oyo to yan Wasiu Akande amyegun gẹgẹ bi Maiyegun ti ilẹ Yoruba naa lo sọ fun un pe oye ẹni to n gbe asa Yoruba ga,

Bakan naa ni wọn tun fikun pe oye Maiyegun ti Kayode Ajulo gba lọwọ aarẹ ọna kakanfo ni lati fi ṣisé.

Ọpọlọpọ ariyanjiyan lo tẹle Alaafin to yan Maiyegun tuntun sọ pe Wasiu ti ọpọ mọ si KWAM 1 ko ni dọbalẹ f'awọn ọba kan mọ lati oni lọ.

Ọdún mọ́kànlá sẹ́yìn ni K1 ti ń béèrè fún oyè Mayegun lọ́wọ́ mi - Alaafin

A moye yii jẹ na, iwo nna! Alaafin ti ilu Oyo, Oba Lamidi Olayiwola Adeyemi kẹta ti fi ilumọọka olorin Fuji, Alhaji Wasiu Ayinde jẹ oye Mayegun ilẹ Yoruba.

Oye naa ti kọkọ da ariyanjiyan silẹ lẹyin ti Alaafin sọ pe Wasiu ti ọpọ mọ si KWAM 1 ko ni dọbalẹ f'awọn ọba kan mọ lati oni lọ.

Amọ Alaafin ṣalaye pe awọn kan ti wọn n pe ara wọn lọba loun n sọ nipa awọn kii ṣe awọn ọba laye bi Ọọni Ile Ife, Awujalẹ ti ilẹ Ijẹbu, Owa Obokun Ileṣa, Alake ti ilẹ Ẹgba ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Alaafin ni Wasiu ko to bẹẹ lati nawọ si iru awọn ọba nla bayii ti wọn ba pade lode.

Alaafin Oyo ṣalaye siwaju sii pe oun ko le ṣe nnkan to tako aṣa ati iṣe Yoruba laelae, o ni oye Mayegun wa ni ibamu pẹlu aṣa Yoruba.

Oríṣun àwòrán, Instagram/K1 the ultimate

O rọ awọn eeyan wi pe ki wọn ye oju opo ayelujara ni ilokulo, Ọba Alaafin ni ilokuko oju opo ayelujara lo jẹ kawọn kan ṣi oun gbọ lori ọrọ oye Mayegun.

Alaafin ni Wasiu gan lo beere fun oye Mayegun ni bi ọdun mọkanla sẹyin nigba to kan si oun laafin pẹlu awọn ọrẹ rẹ.

Alaafin ni oun kọkọ kọ eti ikun si ọrọ naa, lẹyin igba yii loun ṣe iwadii lẹmi ati lara ki oun to gba lati fi Wasiu jẹ oye naa.

Oríṣun àwòrán, Instagram/K1 the ultimate

Ọpọ olorin atawọn eeyan jankan jankan lo ti n ki K1 ku oriire oye Mayegun to ṣẹṣẹ jẹ.

Àkọlé fídíò,

Ifa Priest: ọdún mọ́kànlá ni mo fi ṣe iṣẹ́ agbejọ́rọ̀ kí n tó gbọ́ràn si Ifá lẹ́nu