Iṣẹ́ bọ lọ́wọ́ Ọgágun àgbà Niger lórí ìkọlù tó ṣékú pá ọmọ ogún 89

Aworan awọn ọmọ ogun Mali

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iṣẹ ti bọ lọwọ ọgagun agba ileeṣẹ ologun lorile-ede Niger lọjọ mẹrin sigba tawọn agbebọn pa eeyan mọ́kàndínláàdọ́rùn ún ni ẹka ileeṣẹ ọmọ ọlogun kan.

Eyi ni iye eeyan to pọju lọ to ku lọjọ kan ninu akọsilẹ ilẹ naa.

Lori redio ni wọn ti kede iyọninipo ọgagun Ahmed Mohammed ati awọn ọgagun mẹta miran lẹyin ipade igbimọ alaṣẹ.

Laarin ọdun meji ti ọgagun Mohammed ti wa nipo, niṣe ni ikọlu ti n waye lemọ lemọ pẹlu awọn ikọ agbesunmọmi alakatakiti ẹsin Islam to ni ajọṣepọ pẹlu al-Qaeda ati Islamic State (IS).

Ọgagun Salifu Modi ni wọn fi rọpọ rẹ bi wọn ṣe yọọ nipo tan.

Àkọlé fídíò,

Bakare Mubarak: ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń fẹ́ dúró sí ẹgbẹ́ mí tójú si máa n tì mí

Ẹwẹ, orile-ede Niger ti kede idaro ọlọjọmẹta lati fi kẹdun iku awọn ọmọ ogun mọ́kàndínláàdọ́rùn ún to padanu ẹmi wọn ni ilẹeṣẹ ologun Chingedor camp ni iwọ oorun agbgbe Tillaberi.

Loṣu to kọja ọmọ ogun mọkanlelaadọrin ni awọn agbesunmọmi ṣeku pa nileeṣẹ ologun Inates camp lagbegbe kan naa.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Lọwọlọwọ bayi, aarẹ ilẹ Niger, Mahamadou Issoufou ati awọn aarẹ agbegbe Sahel wa ni ilẹ Faranse nibi ipade pẹlu aarẹ Macron.

Ni ibẹrẹ ipade naa to n waye ni Pau, aarẹ Macron ati awọn olori orileede wọn yi ṣe ayẹsi fawọn ọmọ ogun to fẹmi wọn lelẹ ni Mali loṣu to kọja.

Ọgbẹni Macron ti beere pe ki awọn aarẹ wọn yi fi atilẹyin wọn hansi ikọ ọmọ ogun ilẹ Faranse ẹlẹgbẹrun mẹrin ti ọpọ n bẹnu atẹ lu tohun ti bi ipenija aabọ ti ṣe n peleke si.

Awọn olori orile-ede Chad, Mali, Niger, Burkina Faso ati Mauritania wa nibi ipade naa.

Àkọlé fídíò,

Ifa Priest: ọdún mọ́kànlá ni mo fi ṣe iṣẹ́ agbejọ́rọ̀ kí n tó gbọ́ràn si Ifá lẹ́nu