Aláàfin Ọyọ: Mí o ní kí Wasiu Ayinde má bọ̀wọ̀ fàwọn ọba ilẹ̀ Yorùbá ayafi...

Aworan Alaafin Oyo

Oríṣun àwòrán, Facebook/alaafinoyo

Àkọlé àwòrán,

Mí o ní kí Wasiu Ayinde má bọ̀wọ̀ fàwọn ọba ilẹ̀ Yorùbá ayafi...

Ikubabayeye, Alaafin Ilu Oyo, Ọba Lamidi Adeyemi sọ pe Ọba ti o ba n mu ọti nita gbangba ko yẹ ni ni aa bọwọ fun .

Ọba Lamidi sọ ọrọ yi lasiko to n fi oye da Wasiu Ayinde Marshal lọla gẹgẹ bii Mayegun ilẹ Yoruba nilu Oyo.

Ninu alaye ọrọ rẹ paapaa lori pe oun ko ni ki ẹnikankan ri awọn Ọba fin, Kabiesi ni ''eyikeyi Ọba ti koba bọwọ fun ipo rẹ ti o si n mu ọti tabi to n jo nile igbafẹ ko yẹ lẹni apọnle''

Àkọlé fídíò,

Bakare Mubarak: ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń fẹ́ dúró sí ẹgbẹ́ mí tójú si máa n tì mí

Lori ọrọ tawọn kan n sọ pe Alaafin ni ki Wasiu Ayinde ma dọbalẹ ki awọn Ọba kan, Alaafin ṣalaye pe ''Emi o ni ki Wasiu ma bọwọ faṣa Yoruba, yoo ṣe apọnle awọn Ọba ṣugbọn kii ṣe awọn ti ko fi ara wọn si ipo ọba''

Àkọlé fídíò,

Ifa Priest: ọdún mọ́kànlá ni mo fi ṣe iṣẹ́ agbejọ́rọ̀ kí n tó gbọ́ràn si Ifá lẹ́nu

Awọn Ọba wo gan an ni Wasiu ko le dọbalẹ fun?

Alaafin ko darukọ ọba kankan pe Mayegun ko gbọdọ bọwọ fun wọn ṣugbọn gẹgẹ awọn iwe iroyin Naijiria kan ti ṣe sọ, Alaafin ni oun ko sọ fun Wasiu Ayinde ko tabuku si awọn ọba bi Ooni Ife, Orangun Ila, Awujale Ijebu-Ode, Owa Obokun Ilesa, ati Alake Egba pẹlu awọn miran to fi ara wọn si ipo ọwọ.

Bẹẹ naa ni Alaafin sọ pe Wasiu Ayinde ti beere fun oye Mayegun yii lati nkan bi ọdun mọkanla sẹyin ṣugbọn awọn Oyo Mesi ko faṣẹ si i nigba naa.

Alaafin pari ọrọ rẹ pe ki ẹnikẹni to ba ni ikunsinu pẹlu Wasiu lọ pari rẹ pẹlu rẹ.

''Ki wọn ma fi oju opo ayelujara maa fi doju ija kọ ara wọn''