Supreme Court: Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà yóò ṣe ìdájọ́ àwọn gómìnà meje lónìí

Ganduje
Àkọlé àwòrán Kano Governorship: Ilé ẹjọ sún ìgbẹ́jọ Ganduje sí ogunjọ oṣù kíní

Ilé ẹjọ to ga jùlọ lórílẹ̀-èdè Naijiria, ti sún ìdájọ ẹjọ́ kòtẹmilọrun ti o jẹ́yọ láti ibi ètò ìdìbò gomínà ipinlẹ Kano.

Ìgbìmọ̀ ẹlẹni meje to adajọ àgba Nàjíríà Tanko Muhmmmad sojú lo mu ọjọ́ tuntun ọhun lọ́jọ́ iṣẹ́gun nilu Abuja lásìkò ìgbẹ́jọ kòtẹmilọrun ti olùdíje ẹgbk òṣèlú People's Democratic Party (PDP) Abba Yusuf ninú ìdìbò ọjọ́ kẹsàn Oṣù kéta, ọdun 2019.

ilé ẹjọ ti fẹnukò láti pàdé ni ọjọ ajé Ogunjọ oṣù yiì'láti fẹnu ọ̀rọ̀ jana lóri ìdájọ náà lẹ́yin ti agbẹjọro rẹ̀ ti wijọ nínú ìpẹ̀jọ náà.

Awọn olùjẹ́jọ ni Gomina Gandujè ti ẹgbẹ́ òṣèlú APC àti àjọ elétò ìdìbò Naijiria (INEC).

Supreme Court: Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà a ṣe ìdájọ́ àwọn gómìnà meje lónìí

Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà a ṣe ìdájọ́ àwọn gómìnà meje lónìí

Mukhtar Gidado to jẹ oluranlọwọ pataki si Gomina Bala Muhammed to n tukọ ipinlẹ Bauchi bayii lo fi atẹjade sita.

Ninu atẹjade naa ni wọn ti ṣalaye pé o rẹ gomina naa ni eyi ti wọn ti o ṣi n gba itọju lọwọ nile iwosan ni London bayii.

Gomina Bala Mohammed fohun ranṣẹ sawọn eniyan ipinlẹ Bauchi pe nitootọ lo rẹ oun ni London ṣugbọn ọkan oun balẹ pe didun lọsan a so fun oun ninu idajọ to n lọ lọwọ ni Abuja.

Àkọlé àwòrán Awon agbejoro n pe agbejoro nise ni nile ejo laaro yii ni Abuja

Fọ́fọ́ ní ilé ẹjọ́ kún fún ìdájọ gomina ìpínlẹ̀ Kano, Imo, Sokoto, Benue, Plateau àti Bauchi

Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà a ṣe ìdájọ́ àwọn gómìnà mẹ́fà lónìí

Lana ni ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria sun idajọ awọn gomina mẹfẹẹfa naa si oni Ariwo kò jẹ́! A ti sún ìgbẹ́jọ́ Ganduje, Tambuwal àti Ihedioha sí ọ̀la

Awọn gomina ti ko wọle lo gbe awọn miran ti ajọ eleto idibo INEC kede lọ sile ẹjọ.

Àkọlé àwòrán Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà a ṣe ìdájọ́ àwọn gómìnà mẹ́fà lónìí

Adajọ agba ni wọn so igbẹjọ naa rọ ni ana ọjọ Aje nitori pe ariwo ti pọju ati pe o rẹ ọkan ninu awọn adajọ to maa ṣe idajọ naa.

Loni ni wọn maa dajọ ipinlẹ Kano, Sokoto, Benue, Imo, Plateau , Bauchi ati Adamawa.

Àkọlé àwòrán Ortum fun ra re naa wa ni ikale lati gbo iidajo boya ko tesiwaju tabi bee ko

Awọn agbẹjọro ti kun ile ẹjọ lati ṣoju awọn gomina mẹfẹẹfa ati awọn to pe wọn lẹjọ.

Adajọ meje ati Adajọ Tanko Mohammed to jẹ olori awọn adajọ Naijiria naa ti wa ni ikalẹ fun idajọ naa.

Àkọlé àwòrán Awon agbejoro ti wa ni ikale

Wo awon to n soju awon Gomina mẹfẹẹfa nile ẹjọ ni Abuja lonii.

Ero kun fọfọ ni lati mọ ibi ti ọrọ Ganduje, Ihedioha, Tambuwa, Ortom maa ja si lonii

Àkọlé àwòrán awon agbejoro ti setan

Ẹwẹ, lẹyin iṣẹju diẹ ti igbẹjọ bẹrẹ ni ijoko ile ẹjọ dide nigba ti wọn n gbọ ariwo ero to wa ninu ile ẹjọ ti wọn ko si le kapa rẹ ti adajọ si sun un siwaju di ọjọ kẹrinla, oṣu kinni, ọdun 2020.

Lati wa jẹ ki ero dinku, adajọ agba pasẹ pe ki awọn tọ́rọ̀ kan ma mu wa ju agbẹjọrọ marun un lọ.

Gbogbo eto lo ti to ni sẹpẹ loni nile ẹjọ ni Abuja.

Àkọlé àwòrán Awon ololufe awon gomina mefeefa na ti wa ni ikale

Awon eniyan onikaluku naa ti wa ni ikale lori idajo toni yii.

Àkọlé àwòrán Agbejoro n pe agbejoro ran nise ni loni nile ẹjo ni Abuja

Ibo gomina Ipinlẹ Sokoto

Oludije ibo gomina fẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Sokoto, Ahmad Aminu Waziri lo pe gomina Aminu Waziri Tambuwal to jawe olubori ninu ibo gomina ipinlẹ naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBakare Mubarak: ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń fẹ́ dúró sí ẹgbẹ́ mí tójú si máa n tì mí

Amọ, ile ẹjọ kotẹmilọrun nipinlẹ naa ati ipinlẹ Kaduna da ẹjọ naa nun, eyi lo jẹ ki Aliyu mori le ile ẹjọ to ga julọ l'Abuja.

Koda, atundi ibo tiẹ wa nipinlẹ Sokoto ati Kano, amọ ibi pẹlẹbẹ naa ni ọbẹ fi lelẹ.

Àkọlé àwòrán Awon agbejoro gan an po de ibi pe o dabi ajo ironupiwada ni won pe nile ejo Abuja loni ni

Ibo gomina Ipinlẹ Imo

Oludije ibo gomina fẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Imo, Hope Uzodimma naa yoo mọ lonii bo ya oun lo wọle ibo gomina ipinlẹ Imo.

Àkọlé àwòrán Kakiri Naijiria ni awon agbejoro wonyii ti jade wa soju awon onibara won lotunlosi

Ile-ẹjọ kotẹmilọrun ti kọkọ da ẹjọ rẹ lẹyin to tako bi ajọ eleto idibo INEC ti kede gomina Emeka Ihedioha gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ninu eto idibo naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIfa Priest: ọdún mọ́kànlá ni mo fi ṣe iṣẹ́ agbejọ́rọ̀ kí n tó gbọ́ràn si Ifá lẹ́nu