EFCC: EFCC mú Ọmọ ọdún 17, afurasí mẹ́jọ tó ń ṣe yahoo-yahoo ní Íbàdàn

Awọn afunrasi naa

Oríṣun àwòrán, @officialEFCC

Àkọlé àwòrán,

EFCC mú Ọmọ ọdún 17, afurasí mẹ́jọ tó ń ṣe yahoo-yahoo ní Íbàdàn

Ọwọ ajọ to n gbogun ti iwa ijẹkujẹ lorilẹ-ede Naijiria, EFCC ti tẹ ọmọ ọdun mẹtadinlogun kan ti wọn ni wọn gbamu fun ẹsun lilu jibiti lori ayelujara, iyẹn yahoo-yahoo.

Opin ọsẹ to kọja ni ẹka ajọ naa to wa ni ilu Ibadan mu ọdọmọkunrin naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Abdulrahaman Qozeem atawọn mẹjọ miran kaakiri ilu Ibadan.

Gẹgẹ bi ajọ EFCC ṣe ṣalaye, ọwọ tẹ awọn eeyan naa lẹyin ọpọ iwadii lori iwa ọdaran yahoo-yahoo ti wọn yan laayo.

Oríṣun àwòrán, @officialEFCC

Àkọlé àwòrán,

EFCC mú Ọmọ ọdún 17, afurasí mẹ́jọ tó ń ṣe yahoo-yahoo ní Íbàdàn

Gẹgẹ bi wọn tun ṣe fi kun un, awọn ohun ini olowo iyebiye bii ọkọ ayọkẹlẹ mẹfa pẹlu oniruuru ẹrọ ibanisọrọ, kọmputa alagbeka, iwe irinna silẹ okeere atawọn iwe miran to jẹ ayederu iroyin ni wọn ba lọwọ awọn afurasi naa nigba ti ilẹ mọ ba oloro wọn nita gbangba.

Àkọlé fídíò,

Bakare Mubarak: ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń fẹ́ dúró sí ẹgbẹ́ mí tójú si máa n tì mí