Naira Marley: Naira Marley moribọ, ilé ẹjọ́ tú ẹ̀sùn ìjọ́kọ̀gbé tí wọ́n fi kàn án ká

Naira Marley

Oríṣun àwòrán, Naira Marley/ instagram

Àkọlé àwòrán,

Naira Marley moribọ, ilé ẹjọ́ tú ẹ̀sùn ìjọ́kọ̀gbé tí wọ́n fi kàn án ká

Naira Marley, gbajugbaja olorin taka sufe ni ti bọ lọwọ bebe ẹwọn to n rin fun igba diẹ bayii lori ẹsun jiji ọkọ gbe ti wọn fi kan an.

Arakunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Ademọla Adelekan lo fi ẹsun kan Naira Marley atawọn ọbakan rẹ mẹta pe wọn ji ọkọ oun gbe.

Ni ọjọ Iṣẹgun ni igbẹjọ naa waye lẹyin ti adajọ majisireeti to n gbọ ẹjọ ọhun ti fi aṣẹ lelẹ nigba igbẹjọ to kọja pe ki awọn ọlọpaa waa kan ki wọn si gbe e lọ soko ẹwọn nigba to kuna lati fara han niwaju ile ẹjọ naa.

Àkọlé fídíò,

Bakare Mubarak: ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń fẹ́ dúró sí ẹgbẹ́ mí tójú si máa n tì mí

Amọṣa ọrọ yi pada nigba ti Agbẹjọro fun Naira Marley, Ayọdeji Awokulẹhin ṣalaye fun ile ẹjọ pe ẹsun ti wọn kan an ko lẹsẹ nilẹ ati pe ọkọ ti wọn n sọrọ rẹ naa ti di titun ṣe.

Nigba to n sọrọ lori idi ti Naira Marley ko fi si nile ẹjọ, amofin Awokulẹhin ni ko si lorilẹ-ede Naijiria lo faa.

Àkọlé fídíò,

'Mo fọ́ lójú ṣùgbọ́n mo mọ gbogbo irinṣẹ́ tí mo fi ń ṣe mọkalíìkì'

Ọgbẹni Ademọla Adelekan to fi ẹsun kan Naira Marley ṣalaye pe Naira Marley atawọn ọbakan rẹ lu oun, wọn si ba ọkọ rẹ jẹ ṣugbọn oun ṣetan lati jawọ ninu ẹjọ naa.

Àkọlé fídíò,

Ifa Priest: ọdún mọ́kànlá ni mo fi ṣe iṣẹ́ agbejọ́rọ̀ kí n tó gbọ́ràn si Ifá lẹ́nu

Ẹsun mẹrin to da lori igbimọpọ huwa ọdaran, ole ati lilu eeyan pẹlu didi ọlọpaa lọwọ mimu Naira Marley ni opopona Eko Hotel ni ọjọ karundinlogun, oṣu kejila, ọdun 2019 ni wọn fi kan an.

Lẹyin ti igbẹjọ naa waye ni adajọ Majisireeti, Tajudeen Elias wọgi le ẹjọ naa, to si ni ki Naira Marley maa lọ ni alaafia.