Toyosi Arigbabuwo: Iṣẹ́ aránṣọ̀ ló ń ṣe níbẹ̀rẹ̀ kó tó yà sí iṣẹ́ tíátà

Toyọsi Arigbabuwo

Oríṣun àwòrán, Toyọsi Arigbabuwo

Bi ọdẹ ba ku, ọdẹ nii soro lẹyin ọdẹ, baa ba si ku laa di ere, eeyan kii sunwọn laaye, bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu iku Oloye Toyosi Arigbabuwo to dagbere faye.

Ọpọ awọn ọrẹ rẹ ti wọn dijọ n sisẹ tiata ni wọn ti n salaye nipa iru eeyan ti Arigbabuwo jẹ ati bo se lo igbe aye rẹ nigba to wa loke eepẹ.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, ọkan lara awọn ọrẹ timọtimọ Toyọsi Arigbabuwo ti wọn jọ n sisẹ tiata, Alhaji Musiliu Dasọfunjo salaye pe Arigbabuwo jẹ akikanju eeyan pupọ pupọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Oríṣun àwòrán, Toyọsi Arigbabuwo

Isẹ aransọ ni Toyọsi kọkọ kọ nigba aye rẹ ko to ya si idi isẹ tiata, to si n fi ẹsa ẹkun iyawo kewi, eyi ti awọn eeyan mọ si, ko to wa da ẹgbẹ tiata tiẹ silẹ taa mọ Toyọsi Arigbabuwo Theather Group ni adugbo Alekusọ-Oritamẹrin nilu Ibadan.

Oloogbe Sẹgun Olubukun, toun naa jẹ ilumọọka osere ori itage ni ọga to kọ Arigbabuwo ni isẹ tiata.

Lẹyin ti Arigbabuwo si da ẹgbẹ tiata tiẹ silẹ lo bẹrẹ si ni se ere fun ileesẹ mohunmaworan ijọba apapọ lasiko to wa ni WNTV ko to wa di NTA bayii.

O to si tun maa n kewi fun awọn ileesẹ Redio kaakiri, paapa ni Radio Nigeria to wa nilu Ibadan to fi mọ awọn eto miran lorisirisi.

Ti a ba si n sọrọ nipa ihuwasi oloogbe Arigbabuwo, Dasọfunjo ni o jẹ onisuuru pupọ pupọ, ti kii ba eeyan kankan ja, ti ohunkohun kii si bi ninu, paapa ninu isẹ tiata.

Dasọfunjo salaye pe 2018 ni Arigbabuwo kọkọ bẹrẹ aisan, to si se isẹ abẹ nile iwosan UCH, amọ aisan yii tun pada lọdun 2019, to si tun se isẹ abẹ fun igba keji, lẹyin eyi si ni ko lee jade sita mọ titi ti ọlọjọ fi de baa.

Oríṣun àwòrán, Toyosi Arigbabuwo

Nigba to n sọrọ lori ipa ti ẹgbẹ awọn osere tiata ko lati seranwọ fun Arigbabuwo lasiko to wa lori idubulẹ aisan, Dasọfunjo ni ohun ko lee sọ pato ohun ti ẹgbẹ Tanpan abi ANTP se lati ran Arigbabuwo lọwọ.

Amọ o ni ẹnikọọkan gẹgẹ bii ọrẹ Arigbabuwo lo dide lati sa ipa tiẹ fi seranwọ fun oloogbe naa.

Dasọfunjo ni manigbagbe ni Arigbabuwo jẹ ninu isẹ tiata, to si ti kọ ọpọ eeyan nisẹ tiata, koda ọkan lara wọn ti di ọjọgbọn ni ọgba fasiti bayii.

O wa fọwọ gbaya pe awọn ti n seto lati da ajọ alaanu kan silẹ, taa mọ si Foundation loruks oloogbe Toyọsi Arigbabuwo, eyi ti wọn yoo maa fi se iranti rẹ, ko maa ba parun.

Oríṣun àwòrán, Toyosi Arigbabuwo

Bakan naa, ọrẹ minu miran fun Arigbabuwo ninu isẹ tiata, Gbọlagade Akinpẹlu, tawọn eeyan mọ si Ogun Majek naa sọ tẹdun tẹdun fun BBC Yoruba pe, isẹ tiata ye daada, o lee sere, o lee kọrin, to si tun lee kewi.

O ni Arigbabuwo jẹ eeyan jẹjẹ, ti kii fa wahala lẹsẹ abi se ijangbọn ti awsn yoo si maa ranti rẹ fun ọgbọn to maa fi n pari ija laarin ẹgbẹ ati sna alaafia to maa n san laarin awọn eeyan.

Àlàyé rèé lórí ikú tó pa Toyosi Arigbabuwo

Iku doro, iku ti sika, iku tun ti mu ọkan lara awọn ọlọpọlọ pipe, osere ori itage, Toyosi Arigbabuwo lọ.

Iroyin to tẹ wa lọwọ salaye pe irọlẹ ọjọ Aje ni Toyọsi mi kanlẹ lẹyin aisan olosu mẹfa to ti n baa finra, ti okiki si gbalẹ kan lasiko kan pe o wa lori aisan nile iwosan nla UCH nilu Ibadan.

Toyọsi Arigbabuwo, ẹni ti wọn bi soke eepẹ lọjọ kẹta osu Kẹta ọdun 1948, eyiun ọdun mejilelọgọta sẹyin, lasiko to wa loke eepẹ jẹ ilumọọka nidi isẹ tiata, to si maa n fi ẹkun iyawo dabira lasiko ere sise.

Àkọlé fídíò,

Bakare Mubarak: ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń fẹ́ dúró sí ẹgbẹ́ mí tójú si máa n tì mí

O maa n ke ewi, to si tun jẹ ẹni to gbe ẹsin Islam sori titi to fi tẹri gbasọ, koda oun ni alarina fun ẹgbẹ awọn musulumi to wa lagbegbe Apẹtẹ-Awọtan nilu Ibadan.

Ọsan oni ni wọn yoo fi ara rẹ fun ilẹ nile rẹ to wa ni Awọtan nilu Ibadan