YCE: Ìpínlẹ kọ̀ọ̀kan ní àṣẹ láti dá ààbò bo àwọ̀n ènìyàn wọn

Amotekun
Àkọlé àwòrán,

Ìpínlẹ kọ̀ọ̀kan ní àṣẹ láti dá ààbò bo àwọ̀n ènìyàn wọn

Ẹgbẹ to n risi idagbasoke ilẹ Yoruba, Yoruba Council of Elders ti bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu ohun ti agbejọro ijọba sọ lori idasilẹ ikọ Amọtẹkun to wa fun eto aabo ilẹ Yoruba.

Akọwe ẹgbẹ YCE, Dokita Kunle Olajide lọ sọ wi pe o ku diẹ kaatọ lori ọrọ ti agbẹjọro agba fun ijọba apapọ sọ.

Àkọlé fídíò,

Sunday Igboho: Fulani kò leè dúró, táa bá lo ohun ta jogún lọ́dọ̀ àwọ̀n bàbá wa

O ni iwe ofin ilẹ wa faaye gba ipinlẹ kọọkan pẹlu aṣẹ lati da aabo bo awọn ara agbegbe rẹ labẹ iṣejọba alagbada.

Dokita Olajide ni labẹ ofin, ohun ti ijọba sọ ko bojumu nitori ijọba tiwantiwa la n ṣẹ, ti onikaluku si ni ẹt lati da aabo bo ara wọn, igbimọ kọọkan ni ẹtọ lati da abo bo ara wọn.

Àkọlé àwòrán,

Malami ní ìjọba àpapọ̀ nìkan ló ni ojúṣe ètò ààbò

Bakan naa ni agbajọwọ eniyan lẹtọ lati daabo bo ara wọn.

O fikun un wi pe awọn Gomina ti awọn eniyan dibo yan lẹtọ lati pejọ, ki wọn wa ọna lati ri i wi pe aabo to daju wa fun awọn eniyan ilẹ ati agbegbe wọn.

Akọwe ẹgbẹ YCE naa ni igbeṣẹ ti awọn yoo gbe yoo waye lẹyin ti awọn ba ṣẹ iwadii finifini lori boya ijọba n takọ ikọ Amọtẹkun patapata ti wọn si n lero pe ki wọn tu wọn ka.

Àkọlé fídíò,

BIAFRA at 50: Ìhàlẹ̀ ológun ni Gowon ni ká kọ́kọ́ fi bẹ̀rẹ̀- Aladejẹbi

O ni ohun to difa fun wi pe ijọba fi aaye gba ikọ Sharia ti o ti wa ni awọn ipinlẹ kọọkan ni Ariwa orilẹ-ede Naijira fun ọpọlọpọ ọduin, ati ọlọpaa Hisbah ti wọn ko si se nkan ti ko tọ si wọn.

Naa lo difa fun awọn Amọtẹkun ti awọn gomina gbe kalẹ lati maa ran awọn ọlọpaa lọwọ.

Abubakar Malami ni kò si Gómìnà, yálà ẹyọ kan tàbi lápapọ̀, to ni ẹ̀tọ láti ṣe ìdásílẹ̀ àjọ kankan to níi ṣe pẹ̀lú èètò ààbo.

Idásilẹ̀ Amotekun ko ba òfin ọdún 1999 mu- Malami

Ìjọba orilẹ̀-èdè Naijiria ti ṣe àfiwe ẹgbẹ́ ààbò tuntun ti àwọn gómìnà ẹkun ìwọ̀ òòrun Naijiria dá sílẹ̀ Àmọ̀tẹ́kùn bíi èyí ti wọ́n dá sílẹ̀ lọ́nà ti kò bá òfin mú.

Agbẹjọ́rò àgbà fún ìjọba àpapọ̀ Abubakar Malami (SAN) sàlàyé pé, ọ̀rọ̀ ààbò jẹ ojúṣe ìjọba àpapọ níkàn ni.

Nínú àtẹjáde ti olubadamọ̀ràn pàtàkì lóri igbòhùn sáfẹ́fẹ́ rẹ, Umar Gwandu fọwọ́sí sàlàyé pe, Àmọtẹ́kùn kìí ṣe èyi to ba òfin orilẹ̀-èdè Naijiria mu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àtẹjáde náà ka bayìí pé " ìwé òfin orílẹ̀-èdè Naijiria ti ọdun 1999 ti fi idí rẹ̀ múlẹ̀ pé, ọmọogun orilẹ̀, ọmọogun ojú omi, àti ọmọ omọogun ojú ofurufu, ọlọpàá àti àwọn to farapẹ́ nìkàn lo wà fún ètò ààbò Naijiria."

Àkọlé fídíò,

Bakare Mubarak: ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń fẹ́ dúró sí ẹgbẹ́ mí tójú si máa n tì mí

"Nítori ìdí èyí kò si Gómìnà yálà ẹyọ kan tàbi lápapọ̀ to ni ẹ̀tọ tàbi agbára láti ṣe ìdásílẹ̀ ilé iṣẹ́ tàbí àjọ kankan to níṣe pẹ̀lú èètò ààbo.

Àkọlé àwòrán,

Ìpínlẹ kọ̀ọ̀kan ní àṣẹ láti dá ààbò bo àwọ̀n ènìyàn wọn

Amotekun: Igboho ṣe káre fáwọn gómìnà Yorùbá pé wọ́n fi ohùn kan sọ̀rọ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́

Akọni ọmọ Oodua kan, Sunday Majasọla Adeyẹmọ, ti gbogbo eeyan mọ si Sunday Igboho ti fọwọ gbaya pe oun yoo se atilẹyin fun eto Amotekun.

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho

Atẹjade kan ti Igboho fisita fun awọn akọroyin nilu Ibadan salaye pe awọn gomina ilẹ Yoruba fi ohun kansoso sọrọ fun igba akọkọ lori agbekalẹ eto Amọtekun, idi si ree ti oun yoo fi sa ipa oun lati sugba eto naa.

Àkọlé fídíò,

Ifa Priest: ọdún mọ́kànlá ni mo fi ṣe iṣẹ́ agbejọ́rọ̀ kí n tó gbọ́ràn si Ifá lẹ́nu

Bakan naa lo fikun pe ohunkohun to ba kan iran Yoruba lapapọ lo kan oun naa, ti eto to wa fun ipese aabo to peye naa yoo si mu ilọsiwaju ati idagbasoke ba awujọ ati gbogbo ọmọ ilẹ Kaarọ oojire lapapọ.

Igboho gbosuba fun awọn gomina to wa lẹkun iwọ oorun guusu Naijiria pe wọn se ara wọn ni osusu ọwọ lori eto yii lai fi oniruuru ẹgbẹ oselu ti wọn wa se, eyi to fihan araye pe wọn nifẹ awọn araalu lọkan.

O wa salaye pe "eto Amotekun ko ni ohunkohun se pẹlu ẹgbẹ oselu kankan, bẹẹ lo si kọja agbara ẹda kankan, idi si ree ti gbogbo ọmọ Yoruba fi gbọdọ ri eto naa gẹgẹ bii ipe lati sin ilẹ abinibi wa."

Àkọlé fídíò,

'A rí wàhálà táwọn èèyàn ń kojú nilẹ̀ẹ̀ Yorùbá la ṣe fi "Amotekun" fi ọkàn wọn balẹ̀'

Sunday Igboho wa kesi awọn ọmọ ẹgbẹ OPC, Fijilante atawọn eeyan miran to ni nkan se ninu ipese eto aabo labẹ Amotekun lati fi ọpọlọ se e, ki wọn si ri daju pe wọn ko tẹ ẹtọ awọn araalu mọlẹ.