Imo Supreme Court: Fada Mbaka kéde pé ẹ̀mí mímọ́ ti kọ Ihedioha bíi gómìnà Imo

Fada Ejike Mbaka

Oríṣun àwòrán, Fada Ejike Mbaka

Àkọlé àwòrán,

Fada Mbaka kéde pé ẹ̀mí mímọ́ ti kọ Ihedioha bíi gómìnà Imo

Ọjọ aisun ọdun tuntun, iyẹn ọjọ Kọkanlelọgbọn, osu Kejila, ọdun 2019, lasiko isin ti wọn fi n ki ọdun tuntun kaabọ ninu ijọ Adoration Ministry to wa nilu Enugu, ni asọtẹlẹ nla kan ti waye.

Oludari agba fun ijọ naa, Fada Ejike Mbaka ti tẹnumọ pe asọtẹlẹ ti oun n sọ nipa gomina ipinlẹ Imo, Emeka Ihedioha gbọdọ wa si imusẹ ni, eyi to ti pada wa sẹ bayii Ṣé àsọtẹ́lẹ̀ ìjàmbá iná kò tíì máa ṣe báyìí?.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Mbaka ni ẹmi mimọ lo sọ fun oun pe oludije fun ipo gomina fẹgbẹ oselu APC, Hope Uzodinma ni yoo pada wa yẹ aga mọ gomina to wa nipo naa lọwọ nidi ninu ọdun tuntun.

Àkọlé àwòrán,

Fada Mbaka kéde pé ẹ̀mí mímọ́ ti kọ Ihedioha bíi gómìnà Imo

Lasiko ti asọtẹlẹ naa waye, ẹjọ ti Uzodinma pe lati tako esi ibo to gbe Ihedioha wọle si wa nile ẹjọ.

Amọ, ojisẹ Ọlọrun ninu ijọ Katoliki naa n tẹnumọ pe gbogbo awọn eeyan to n yọ suti ete si ohun lori asọtẹlẹ naa, ni yoo pada wa yin oun lawo lẹyin to ba sẹ tan.

Nigba to tun di ọjọ isinmi akọkọ ninu ọdun tuntun ni Mbaka tun ke tantan pe ki gomina Ihedioha maa palẹ ẹru rẹ mọ nile ijọba nitori gomina tuntun maa to de.

Àkọlé fídíò,

Bakare Mubarak: ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń fẹ́ dúró sí ẹgbẹ́ mí tójú si máa n tì mí

Mbaka ni ẹmi mimọ ti kọ gomina Ihedioha, ti ireti tuntun pẹlu asia ọtun yoo si duro nile ijọba ipinlẹ Imo laipẹ.

Mbaka ni "Emi ko mọ bi asọtẹlẹ yii yoo se di mimusẹ, sugbọn ohun kansoso ti mo ri ni ireti, ayọ ati ijọba tuntun nipinlẹ Imo. Koda bi Ihedioha bori nile ẹjọ kekere ati ti ileẹjọ Kotẹmilọrun, eyi ko tumọ si pe yoo bori nile ẹjọ to ga julọ."

Àkọlé fídíò,

'A rí wàhálà táwọn èèyàn ń kojú nilẹ̀ẹ̀ Yorùbá la ṣe fi "Amotekun" fi ọkàn wọn balẹ̀'

Asọtẹlẹ naa si ti wa si imusẹ nirọlẹ ọjọ Isẹgun nigba ti ile ẹjọ to ga julọ nilẹ Naijria kede pe gomina Emeka Ihedioha kọ lo moke ninu ibo gomina, Hope Uzodinma ni

Ileẹjọ naa ni ki wọn bura lọgan fun gomina tuntun, Hope Uzodinma, lati gba ipo Ihedioha lọgan.

Ihedioha di gómìnà àná ní Imo, Uzodinma di gómìnà tuntun

Ile ẹjọ to ga julọ nilẹ wa ti kede pe ofuutu fẹẹtẹ, aasa ti ko ni kanhun ni ibo to gbe gomina ipinlẹ Imo, Emeka Iheodiha wọle.

Irọlẹ ọjọ Isẹgun ni igbimọ ẹlẹni meje nile ẹjọ to ga julọ nilẹ wa, ti adajọ Tanko Muhammad ko sodi, dijọ panupọ kede pe oludije fun ẹgbẹ iselu APC, Hope Uzodinma lo moke ninu ibo gomina to waye nipinlẹ naa lọjọ kẹsan an, osu Kẹta, ọdun 2019.

Oríṣun àwòrán, Hope Uzodinma

Adajọ Kudirat Kekere Ẹkun to ka idajọ alajumọse naa wa pasẹ pe ki wọn gba iwe ẹri moyege ibo ti wọn fun Ihedioha lọgan.

Bakan naa lo tun pasẹ pe ki wọn gbe iwe ẹri moyege ibo tuntun fun Hope Uzodinma loju ẹsẹ, ki wọn si bura fun un lọgan.

Bẹẹ ba gbagbe, laipẹ yii ni alufa ijọ Aguda kan, Fada Mbaka sọ̀ asọtẹlẹ pe ile ẹjọ to ga julọ yoo yẹ aga mọ gomina Ihedioha nidi.

Àkọlé fídíò,

Ifa Priest: ọdún mọ́kànlá ni mo fi ṣe iṣẹ́ agbejọ́rọ̀ kí n tó gbọ́ràn si Ifá lẹ́nu