Biafra at 50: Ó tó mílíọ̀nù mẹ́ta èèyàn tó bá ogun náà lọ

Ọgagun Odumegwu Ojukwu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ọgagun Odumegwu Ojukwu n sọrọ nibi ipade alaafia laarin Biafra ati Naijiria. Oun lo pe fun Biafra

Ogun abẹle ni Naijiria, ti a tun mọ si ogun Biafra, waye laarin ijọba orilẹ-ede Naijiria ati awọn ípinlẹ Biafra to yapa laarin ọjọ kẹfa, oṣu Keje, ọdun 1967 si ọjọ kẹẹdogun, oṣu Kinni, ọdun 1970.

Oni ọjọ Aje gan si lo pe ọdun mẹtalelaadọta ti ogun abẹle Baifra naa bẹrẹ.

Ogun naa bẹrẹ nitori ikunsinu lori ọrọ oṣelu, ọrọ aje, ẹya, àṣà, ati ẹsin to ti wa nilẹ ṣaaju ki orilẹ-ede Britain to o tu Naijiria silẹ l'oko ẹru lọdun 1960.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ohun to fa ogun naa ni pato l'ọdun 1966 ni ija ẹlẹyamẹya ati ẹsin to waye ni apa Ariwa Naijiria, iditẹ gbajọba, ati bi awọn kan ṣe gbogun ti awọn ẹya Igbo to n gbe ni apa Ariwa Naijiria.

Bakan naa ni ija lori ẹni ti yoo maa ṣakoso ipese epo-rọbi to wa ni agbegbe Niger Delta, naa ko ipa pataki.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Awọn to fi ara wọn silẹ lati jagun fun orilẹ-ede Biafra

Ibéré ọrọ:

Ni nkan bi ọdun 1940 si 1950, awọn ẹgbẹ oṣelu nilẹ Yoruba ati Igbo lo n lewaju ija fun ominira kuro lọwọ orilẹ-ede Britain. Wọn si tun n fẹ ki Naijiria o jẹ pipin si ipinlẹ kekeeke.

Amọ awọn akọsilẹ kan sọ pe igbesẹ wọn yii ko dun mọ awọn olori apa Ariwa lọrun, ti wọn si n bẹru pe ominira yoo fi agbara fun awọn to wa ni Gusu lati maa dari ọrọ aje ati oṣelu. Eyi mu ki wọn o faramọ iṣejọba orilẹ-ede Britain.

Àkọlé fídíò,

BIAFRA at 50: Ìhàlẹ̀ ológun ni Gowon ni ká kọ́kọ́ fi bẹ̀rẹ̀- Aladejẹbi

Eyi mu ki awọn olori ni Ariwa o sọ pe ki orilẹ-ede Naijiria o wa ni pinpin si ẹkun mẹta nikan lo le mu ki awọn o faramọ ominira, ki Ariwa si ni agbegbe to pọju.

Afojusun awọn olori ẹya Yoruba ati Igbo lati gba ominira, mu ki wọn o faramọ ibeere awọn eniyan Ariwa.

Gomina ologun ni agbegbe Gusu-Ila oorun, Ọgagun Odumegwu Ojukwu, ati ile aṣofin agbegbe naa kede pe agbegbe Guusu-Ila oorun ti yapa kuro lara orilẹ-ede Naijiria, nitori bi wọn ṣe pa awọn eniyan ẹya Igbo ni ipakupa ni agbegbe Ariwa, ati mago-mago eto idibo.

Wọn kede pe Biafra ni awọn yoo maa pe orilẹ-ede tuntun naa; orilẹ-ede olominira, ni ọgbọnjọ, oṣu Karun un, ọdun 1967.

Ọpọlọpọ ipade lo waye laarin ijọba Naijiria ati awọn olori Biafra, paapa eyi to waye ni Aburi, l'orilẹ-ede Ghana (Aburi Accord).

Abajade ati adehun ti wọn fẹnuko le ni ipade alaafia naa f'oriṣanpọn, ogun si bẹrẹ.

Àkọlé fídíò,

Bakare Mubarak: ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń fẹ́ dúró sí ẹgbẹ́ mí tójú si máa n tì mí

Ibẹrẹ Ogun Abẹle

Ijọba Naijiria ko awọn ọlọpaa sita lati gba agbegbe to yapa pada.

Ọjọ kẹfa, oṣu Keje, ọdun 1967, si ni ogun naa bẹrẹ ni pẹrẹwu, nigba ti awọn ọmọ ogun Naijiria gba ọna meji wọ ilẹ Biafra.

Wọn gba Ariwa ilẹ Biafra ati ilu Nsukaa wọle. Ọna meji si ni wọn pin awọn ọmọ ogun si.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Awọn ọmọ ogun Biafra n yẹ awọn ibọn wọn wo ni imura silẹ

Amọ ṣa, awọn ọmọ ogun Biafra naa fi ija da orilẹ-ede Naijiria lohun nigba ti wọn wọ Iwọ-oorun Naijiria lọjọ kẹsan an, oṣu Keje.

Ilu Benin ni wọn gba wọle, ko to o di pe awọn ọmọ ogun da wọn duro ni ilu Ọrẹ lọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹjọ.

Wọn ko fi bẹ ni idojukọ kankan ni awọn agbegbe to yi ilẹ Yoruba ka, nitori naa ni wọn ṣe gba agbegbe naa.

Bo tilẹ jẹ wi pe ijọba Naijiria pada gba ilu Benin pada ni ogunjọ, oṣu Kẹsan an, awọn eniyan Biafra mu ipinnu wọn ṣẹ nipa kikapa awọn ọmọ ogun Naijiria kan.

Laarin ọdun kan ti ogun naa bẹrẹ, ijọba Naijiria fi awọn ọmọ ogun yi agbegbe Biafra ka, ti wọn si gba awọn ileeṣẹ ifọpo wọn, ati ti ilu Port Harcourt.

Ijọba ilẹ Biafra fi ẹsun kan pe Naijiria n lo ebi ati pipa awọn eniyan wọn nipakupa lati fi bori ogun naa, wọn si beere fun iranlọwọ lati ilẹ okeere.

Ni ọdun 1968, aworan awọn ọmọde ti ebi n pa, ti awọ wọn si ri rada-rada gba ori awọn amohunmaworan nilẹ alawọ funfun kan.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ni ọdun 1968, aworan awọn ọmọde ti ebi n pa, ti awọ wọn si ri rada-rada gba ori awọn amohunmaworan nilẹ alawọ funfun.

Wahala airi ounjẹ jẹ yii di nkan ti awọn orilẹ-ede ilẹ okeere n jiroro le lori laarin ara wọn, eyi si mu ki afikun de ba bi wọn ṣe n nawo fun orilẹ-ede miran.

Bakan naa ni awọn ajọ ti kii ṣe tijọba n di gbaju-gbaja.

Ọpọlọpọ awọn ajọ alaanu si bẹrẹ si fi ounjẹ, oogun, ati nkan ijagun (bi awọn kan ṣe sọ) ranṣẹ si Biafra.

Bakan naa ni ijọba Naijiria fi ẹsun kan Biafra pe oun lo awọn ọmọ ogun ilẹ okeere lati le fa ogun naa gun.

Orilẹ-ede United Kingdom ati Soviet Union ni alatilẹyin gboogi fun ijọba Naijiria, nigba ti France, Israel ati awọn orilẹ-ede kan faramọ Biafra.

Àkọlé fídíò,

Wo imọran Fọlọrunṣọ Alakija fun awọn ọdọ adulawọ

Ni oṣu Kẹfa, ọdun 1969, Biafra yawọ Naijiria pẹlu agbara lati le kọlu wọn lojiji.

Awọn ọmọ ogun ilẹ okeere si ran wọn lọwọ nipa ounjẹ, oogun ati nkan ijagun.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Awọn ọmọ ogun Biafra n ṣe ajọyọ pẹlu ibọn wọn lori ọkọ ijagun Naijiria ti wọn bajẹ lọdun 1968

Awọn ọmọ ogun ilẹ okeere yii kọlu ibudo ijagun Naijiria to wa ni Port Harcourt, Enugu, Benin ati Ughelli, ti wọn si ba ọpọ awọn baalu ijagun wọn jẹ.

Bo tilẹjẹ pe ikọlu Biafra naa ba Naijiria lojiji, ko pẹ pupọ ti wọn fi gbẹsan.

Ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kejila, ọdun 1969 ni Naijiria tun kọlu wọn. Ọgagun Olusegun Obasanjo, to pada di aarẹ Naijiria lo lewaju awọn ọmọ ogun to kọlu wọn.

Ọjọ keje, oṣu Kinni, ọdun 1970 si ni wọn ṣe ifilọlẹ ikọlu ikẹhun ti wọn pe ni "Operation Tail-Wind".

Ọjọ kẹtala, oṣu Kinni si ni ogun naa pari nigba ti awọn ọmọ ogun Biafra jọwọ ara wọn.

Ọjọ diẹ ṣaaju ọjọ naa ni Ojukwu sa kuro ni ilu; o wa baalu lọ si orilẹ-ede Cote d'Ivoire, to si fi igbakeji rẹ, Philip Effiong, silẹ lati mojuto jijọwọ ara wọn fun ijọba Naijiria.

Àkọlé fídíò,

'A rí wàhálà táwọn èèyàn ń kojú nilẹ̀ẹ̀ Yorùbá la ṣe fi "Amotekun" fi ọkàn wọn balẹ̀'

Didi ti wọn ti awọn ọna to wọ ilẹ Igbo fa ìyàn kaakiri ilẹ naa, to si jẹ pe awọn akọsilẹ kan sọ pe eniyan to to ẹẹdẹgbẹta ẹgbẹrun (500 thousand) si miliọnu meji l'awọn ọmọ Biafra tó kú nitori airi ounjẹ jẹ.

Eyi ko tun yọ awọn ọmọ ogun bi ọgọrun un ẹgbẹrun silẹ.

Awọn kan tilẹ sọ pe eniyan bi miliọnu mẹta lo ku nitori ogun naa.

Àkọlé fídíò,

#Queen Dihya: Obinrin tó gbógun tàwọn agbésùnmọ̀mí ni Algeria