Omolola Ajayi: Gloria Bright ní ọ̀gá òun kọ̀ láti sanwó oṣù fún òun lẹ́yìn oṣù mẹ́ta

Àkọlé fídíò,

Lebanon: Iṣẹ́ tí kòsí ní Naijiria, la ṣe lọ ṣe ọmọ ọ̀dọ̀ ní Lebanon

Ọ̀gá mi fẹ́ fi tipá bámi lòpọ̀ ní Lebanon àmọ́ ìjọba yọ mí l'óko ẹrú - Ọmọ Nàíjíríà míì

Ẹni ọdún mẹ́tàlélógún kan ti darapọ̀ mọ́ ẹbí rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Kwara lẹ́yìn tórí kóo yọ lóko ẹrú orílẹ̀-èdè Lebanon.

Ori ti ko ọmọ Naijiria mii, Gloria Taye Bright yọ loko ẹru lorilẹ-ede Lebanon, nibi to ti n ṣe iṣẹ ọmọ ọdọ.

Obinrin ẹni ọdun mẹtalelọgbọn ọhun ni ori ko yọ, lẹyin to figbe ta lori itakun agbaye, to si ṣalaye ohun toju rẹ ri lorilẹ-ede ọhun.

Gloria sọ pe, ọga ti oun n ba ṣeṣẹ kọ lati sanwo oṣu oun, bo tilẹ jẹ pe oun ti ṣe iṣẹ fun oṣu mẹta, ati pe ọpọ igba ni ọga naa ma n gbiyanju lati fi ipa ba oun lopọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ṣalaye pe iṣẹ olukọ ede Gẹẹsi ni wọn sọ pe oun yoo lọ se lorilẹ-ede Lebanon, ṣugbọn iṣẹ ẹru ni wọn fi oun ṣe lẹyin to de ọhun.

Ni bayii, obinrin naa ti darapọ pẹlu awọn ẹbi rẹ ni olu ileeṣẹ ajọ aabo ara ẹni labo ilu ti ipinlẹ Kwara, nilu Ilorin.

O sọ fun awọn akọroyin pe, ọpọ awọn ọmọ Naijiria to wa ni Lebanon ni iṣẹ ti wọn n ṣe yatọ si iṣẹ ti wọn lero pe wọn yoo ṣe, ti wọn ba de ọhun.

Àkọlé fídíò,

Bakare Mubarak: ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń fẹ́ dúró sí ẹgbẹ́ mí tójú si máa n tì mí

Gloria sọ siwaju sii pe, ko si owo dọla lorilẹ-ede Lebanon bayii, nitori naa, o ṣeṣe ki ọpọ awọn Naijiria to n ṣiṣẹ lọhun ma ri owo iṣẹ ti wọn n ṣe gba.

Àkọlé àwòrán,

O ni iṣẹ olukọ ede Gẹẹsi ni wọn sọ pe oun yoo lọ ṣe lorilẹ-ede Lebanon

Lẹyin naa lo rọ awọn ọmọ Naijiria to n gbero ati lọ si Lebanon lati tu ero wọn pa, nitori nnkan ko ri bi wọn ṣe ro.

Bi ẹ ko ba gbagbe, inu ọsẹ ti a wa yii ni ori ko Omolola Ajayi yọ l'oko ẹru Lebanon, lẹyin to fi fidio kan lede leyi to gba oju opo Facebook kan.

Àkọlé fídíò,

Ifa Priest: ọdún mọ́kànlá ni mo fi ṣe iṣẹ́ agbejọ́rọ̀ kí n tó gbọ́ràn si Ifá lẹ́nu