BIAFRA War armed forces remembrance: Ìhàlẹ̀ ológun ni Gowon ni ká kọ́kọ́ fi bẹ̀rẹ̀, ẹsẹ̀ akẹ́gbẹ́ mi méjèjì ló gé - Aladejebi

BIAFRA War armed forces remembrance: Ìhàlẹ̀ ológun ni Gowon ni ká kọ́kọ́ fi bẹ̀rẹ̀, ẹsẹ̀ akẹ́gbẹ́ mi méjèjì ló gé - Aladejebi

Awolowo lo jawe olubori ninu idibo ọdun 1966 - Aladejẹbi.

Ogun Biafra jẹ ogun abẹle ti Naijiria ja pẹlu awọn iran Igbo lọdun 1967 si ọdun 1970.

Ogun yii sọ ọpọ ẹmi ati dukia nu ni eyi ti Naijiria n ṣe iranti aadọta ọdun to waye.

Ọkan lara ọmọ ogun ilẹ to kopa ninu ogun nigba naa, Baba Gabriel Aladejẹbi ba BBC rin irinajo ohun ti oju rẹ ri lasiko ogun Biafra.

Gabriel sọ nipa awọn igbesẹ ati aṣẹ ti Ọgagun Yakubu Gowon pa lasiko ogun yii titi di ọjọ ti Phillip fi kede pe iran Igbo ko ja ogun Biafra mọ lọdun 1970

Baba Aladejẹbi sọ nipa awọn ẹmi, dukia ati ohun ti o ba ogun Biafra rin nigba naa ati ero awọn eniyan to kopa ninu ogun ọhun

Aladejẹbi sọ nipa iya ati ipenija ti awọn ọmọ ogun fẹyinti n koju ni isinyi ni eyi ti ijọba ko pese iranlọwọ bi o ti yẹ.