Kara Bridge: Ó kéré tán, ọkọ̀ yóò lo wákàtí mẹ́ta kó tó bọ́ lójú ọ̀nà Kara tó dí pa

Sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ ni marosẹ Eko si Ibadan

Ọpọ awọn eeyan to n gba opopona Berger si ori afara Kara nilu Eko lo ti n figbe ta bayii lori isoro sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ nla ti wọn n koju lagbegbe naa.

Isoro oju ọna to di pa naa waye nitori bi ileesẹ Berger to n se atunse abala kan ni opopona Marosẹ Ibadan silu Eko, se tun ti abala kan oju ọna naa pa, eyi to lọ si Ibadan lati Eko.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bẹẹ ba gbagbe, oju awọn araalu ri mabo lopin ọdun 2019 nigba ti ileeẹ to n se oju sna ọhun ti abala kan pa ladugbo Kara si Berger, eyi to nira fun ọpọ eeyan lati gba oju ọna ọhun wọ ilu Eko.

Lọwọlọwọ bayii, wahala naa tun ti peleke si lati Ọjọ Aje, ọjọ Kẹfa osu Kinni ọdun 2020 nigba ti wọn tun ti abala titi naa pa, ti ọpọ awọn eeyan to n gba opopona ọhun si n lo wakati mẹta, o kere tan, ki wọn to ri ọna kọja.

Iroyin to n tẹ wa lọwọ bayii ti wa fidi rẹ mulẹ pe, se ni awọn ọkọ duro lai lee lọ siwaju abi sẹyin lopopona marosẹ to wọ Ibadan si Eko ati eyi to lọ lati Eko si Ibadan nitori ọna ti wọn ti pa naa.

Nigba to n sọrọ lori bi wọn se ti ọna ọhun pa, Ademọla Kuti, tii se oludari feto isẹ ode nileesẹ to wa fọrọ isẹ ode labẹ ijọba apapọ, fi ọwọ gbaya pe isẹ yoo ya kiakia lori atunse opopona naa nitori akoko ẹẹrun ti a wa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBIAFRA at 50: Ìhàlẹ̀ ológun ni Gowon ni ká kọ́kọ́ fi bẹ̀rẹ̀- Aladejẹbi

Kuti fikun pe ti yoo ba fi di idaji osu Keji shun 2020, o seese ki awọn isẹ atunse oju ọna Ibadan si Eko ti buse ki ojo too bẹrẹ.

Ìjàmbà ọkọ̀ akẹ́rù ní Ikòròdú fa súnkẹrẹ-fàkẹrẹ ọkọ̀ ní Márosẹ̀

Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Ijamba ọkọ Akẹru naa n fi kun asiko irinajo awọn eniayn

Laarọ ni wọn ni awọn ọkọ akẹru meji kọkọ gba ara wọn ni agbegbe Ikorodu ni ipinlẹ Eko ni Guusu Naijiria.

Iroyin ni ijamba yii fa sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ ni eyi to fi kan awọn ọkọ to n rin ni opopona mejeeji awọn to n lọ ati awọn to n bọ pada wọnu Eko.

Ko pẹ ti ijamba yii ṣẹlẹ ni wọn ni awọn ajọ ẹṣọ alaabo oju popo (FRSC) ti de sibẹ lati pese iranwọ to yẹ.

Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Ìjàmbà ọkọ̀ akẹ́rù ní Ikòròdú fa súnkẹrẹ-fàkẹrẹ ọkọ̀ ní Márosẹ̀

Awọn eniyan ti n gbọ sọ fun ara wọn lati yago fun opopona Ikorodu bayii nitori pe ijamba to ṣẹlẹ nitosi agbegbe Obanikoro naa ko kere

Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Ìjàmbà ọkọ̀ akẹ́rù ní Ikòròdú fa súnkẹrẹ-fàkẹrẹ ọkọ̀ ní Márosẹ̀

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni pe awọn oṣiṣẹ to n mojuto igbokegbodo ọkọ nipinlẹ Eko, LASTMA ti de sibẹ wọn si ti di ọna naa pa ki wọn le raaye wọ awọn ọkọ akẹru naa kuro.

Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Ijamba oko akeru ni Obanikoro ti fa sunkere fakere oko

Idásilẹ̀ Amotekun ko ba òfin ọdún 1999 mu- Malami

Ọ̀gá mi fẹ́ fi tipá bámi lòpọ̀ ní Lebanon àmọ́ ìjọba yọ mí l'óko ẹrú - Ọmọ Nàíjíríà míì

Bí ìtàn ayé Toyosi Arigbabuwo ṣe lọ rèé láti ẹnu Musiliu Dasofunjo àti Ogun Majek

Àsọtẹ́lẹ̀ Fada Mbaka, tó yẹ àga mọ́ gómìnà Imo nídìí rèè

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBIAFRA at 50: Ìhàlẹ̀ ológun ni Gowon ni ká kọ́kọ́ fi bẹ̀rẹ̀- Aladejẹbi