Ladoke Akintola: Ó pé ọdún mẹ́rìnlélàádọ̀ta tí Akintola kú, ìdí abájọ ìja rẹ̀ pẹ̀lú Awolowo rè é

Samuel Ladoke Akintola ati Obafemi Awolowo Image copyright Other
Àkọlé àwòrán Ladoke Akintola: Ó pé ọdún mẹ́rìnlélàádọ̀ta tí Akintola kú, ìdí abájọ ìja rẹ̀ pẹ̀lú Awolowo rè é

Iku ogun nii pa Akikanju, iku odo nii pa omuwẹ.

Oni ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹẹdogun, oṣu kinni, ọdun 2020 lo pe ọdun mẹrinlelaadọrin tawọn ologun ṣekupa Samuel Ladoke Akintola to jẹ Aare Ona Kakanfo kẹtala ilẹ Yoruba.

Akintola to jẹ alakoso ijọba apa iwọ oorun Naijiria nigba naa wa lara awọn gbajugbaja oloṣelu tawọn ologun ti wọn ditẹ gbajọba awarawa lọdun 1966.

Ilu Ibadan tii ṣe olu-ilu ijọba apa iwọ oorun Naijiria ni wọn pa Akintola si ninu iditẹ-gbajọba ti wọn ti pa ọpọ oloṣelu to jẹ ọmọ ẹgbẹ NPC (Northern People's Congress).

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBIAFRA at 50: Ìhàlẹ̀ ológun ni Gowon ni ká kọ́kọ́ fi bẹ̀rẹ̀- Aladejẹbi

A bi Akintola lọjọ kefa, oṣu keje, ọdun 1910 si idile Akintola Akinbola and Akanke niluu Ogbomoṣo to wa labẹ ipinlẹ Oyo bayii.

Nigba ti Akintola wa ni kekere ni baba rẹ to jẹ oniṣowo ko ẹbi rẹ lọ si ilu Minna.

Eto ẹkọ Akintola

Akintola bẹrẹ eto ẹkọ rẹ nile iwe Church Missionary Society school niluu Minna to jẹ olu-ilu ipinlẹ Niger lonii.

Akintola pada si ilu Ogbomoṣo lọdun 1922 lati maa gbe pẹlu awọn baba baba rẹ, nibẹ lo ti lọ ile iwe Baptist day school.

Akintọla tẹsiwaju ẹkọ rẹ nile iwe Baptist College lọdun 1925.

Akintola ṣiṣẹ olukọ nile iwe Baptist Academy lati ọdun 1930 si ọdun 1942, ko too lọ ṣiṣẹ ni ile iṣẹ Reluwe.

Image copyright Other
Àkọlé àwòrán A bi Akintola lọjọ kefa, oṣu keje, ọdun 1910 si idile Akintola Akinbola and Akanke niluu Ogbomoṣo to wa labẹ ipinlẹ Oyo bayii.

Akintola wọ agbo oṣelu

Lẹyin to kẹkọọ gboye tan nilẹ Gẹẹsi gẹgẹ bi agbẹjọro, Akintola pada si Naijiria lọdun 1949.

Lẹyin naa lo darapọ mọ awọn ti wọn ti kawe gboye mii lapa iwo oorun Naijiria lati da ẹgbẹ oṣelu Action Group (AG) silẹ pẹlu ifari Oloye Obafemi Awolowo.

Akintola kọkọ di ipo oludamọran lori ọrọ ofin ẹgbẹ naa mu ko to di igbakeji adari ẹgbẹ oṣelu AG lọdun 1953 lẹyin iku Bode Thomas.

Image copyright Other
Àkọlé àwòrán Lẹyin to kẹkọọ gboye tan nilẹ Gẹẹsi gẹgẹ bi agbẹjọro, Akintola pada si Naijiria lọdun 1949.

Gẹgẹ bi igbakeji adari ẹgbẹ, Akintola ko ṣiṣẹ ninu ijọba apa iwọ oorun Naijiria ti Oloye Awolowo jẹ alakoso rẹ.

Ṣugbọn oun ni adari ẹgbẹ osẹlu AG nile aṣoju-ṣofin Naijiria lapaapọ nibi to ti jẹ olori ẹgbẹ oṣelu alatako.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBakare Mubarak: ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń fẹ́ dúró sí ẹgbẹ́ mí tójú si máa n tì mí

Akintọla jẹ minisita eto ilera, ibaraẹnisọrọ ati minisita ọkọ ofurufu.

Ọrọ lori iṣejọba ajumọlo ninu ẹgbẹ oṣelu AG lo mu ki edeaiyede ṣẹlẹ laarin Akintola ati Awolowo.

Akintola tako igbesẹ ẹgbẹ AG pẹlu idari Awolowo lori asopọ pẹlu ẹgbẹ oṣelu mii, Akintola ni awọn ẹya Igbo ni wọn n jẹ anfaani eto ọhun ju.

Edeaiyede laarin Awolowo ati Akintola

Awolowo fẹsun kan Akintola pe o fẹ fi eeru gba ipo olori ẹgbẹ oṣelu AG mọ oun lọwọ.

Rogbodiyan bẹ silẹ nile igbimọ aṣofin ijọba apa iwọ oorun Naijiria lẹyin tawọn aṣofin kan dibo lati yọ Akintola nipo lọdun 1962.

Rogbodiyan ọhun lo jẹ ki ile aṣofin ijọba apa iwọ oorun Naijiria pin si meji.

Rogbodiyan yii lo jẹ ki olootu ijọba Naijiria nigba naa, Sir Abubakar Tafawa Balewa kede ko nile o gbele nilẹ Yoruba.

O si fi Oloye M.A Majekodunmi, to jẹ minisita eto ilera nigba naa gẹgẹ bi alakoso ijọba.

Image copyright Getty Images

Lẹyin ọ rẹyin, Akintola pada gba ipo rẹ gẹgẹ bi alakoso ijọba apa iwọ oorun Naijiria lọdun 1963.

Akintola tun wọle ibo gbogbogbo ọdun 1965 ṣugbọn o dije ninu eto idibo naa gẹgẹ bi adrari ẹgbẹ oṣelu tuntun Nigerian National Democratic Party (NNDP).

Ẹgbẹ oṣelu NNDP ni ajọsẹpọ pẹlu Northern People's Congress (NPC) to n ṣakoso ijọba apapọ nigba naa.

Idile Akintola

Akintola ṣe igbeyawo pẹlu Oloye Faderera Akintola, Eleduwa si fi ọmọ marun un jinki wọn.

Meji ninu ọmọ rẹ, Oloye Yomi Akintola and Dokita Abimbola Akintola naa jẹ minisita keji fun eto inawo.

Yomi Akintola tun fi igba kan jẹ aṣoju ijọba orilẹ-ede Naijiria ni Hungary, bakan naa ni iyawo ọmọ rẹ kan, Dupe Akintola jẹ aṣoju ijọba Naijiria ni Jamaica.